ỌWỌ TẸ MỌNDAY TO N JI ADIẸ GBE L’OWODE YEWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ




Monday, July 1, 2019

ỌWỌ TẸ MỌNDAY TO N JI ADIẸ GBE L’OWODE YEWA

Wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun, wọnyii lọrọ to lọ nibamu pẹluu bọwọ ṣe tẹ ọdọmọkunrin kan ti wọn loo fẹran lati maa ji adiẹ gbe niluu Owode Yewa, ti wọn si n kọrin “Akiti the ghost” fun un.
 
AWIKONKO gbọ pe iluu naa yoo sinmi bayii, tawọn nnkan ọsin bii adiẹ ko nii ye e sọnu bii ti tẹlẹ mọ.

Ẹsun Mọnday ni wọn pe orukọ ọdọmọkunrin naa ti wọn lọmọ ogun ọdun pere ni, ati pe iṣẹ ni wọn lo n kọ lọwọ lagbegbe Tẹjuọla, Owode Yewa. Wọn ni lọpọ igba tawọn eeyan ba n wa adiẹ wọn, anjọọnu ni wọn lero pe o n gbe awọn adie naa lọ.

Wọn lawọn eeyan ti kọju ija sira wọn lọpọ, ti wọn ti fẹsun kan ara wọn lori adiẹ to n sọnu, lai mọ pe Mọnday lo wa nidi ẹ. Igba to ya ni wọn lawọn eeyan gba kamu pe o ṣee ṣe ko jẹ pe anjọọnu afẹfẹ lo kundun lati maa jẹ adiẹ lasiko yi.

Nigba taṣiri maa tu, wọn ni ṣe lori tako Mọnday nigba to gba adugbo ọtọọtọ meji lọ, iyẹn adugbo Tẹjuọla ati adugbo Mọlu Audu, to si lọọ ji adiẹ wọn ko, awọn kan ti wọn rin sasiko la gbọ pe wọn rii nibi to ti n ji adiẹ gbe sabẹ aṣọ.

Lojiji ni wọn yọ sii to si fẹ maa ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ṣugbọn ti wọn gba tẹle, ta a si gbọ pe pẹluu iranlọwọ awọn ẹṣọ alaabo So Safe Corps ni wọn fi rii mu. Bọwọ ṣe tẹ lo bẹrẹ sii ka boroboro pe atijẹ lo sun oun debẹ.

Mọnday jẹwọ pe iya kan loun maa n ta awọn adiẹ naa fun ni gbogbo ọjọ ni wọn ba ti n na ọja Owode, ati pe ẹẹdẹgbẹta (500) naira loun maa n ta adiẹ kan ṣoṣo fun mama naa.

Lẹyin iwadii la gbọ pe wọn lọọ fa a le awọn ọlọpaa Owode Yewa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment



PÍN-IN KÁÀKIRI