Ẹ RÌN JÌNNÀ SIPINLẸ OGUN LÁSÌKÒ ÀTI LẸ́YÌN ILÉYÁ - Ọ̀GÁ FIJILANTÉ PÀRỌWÀ FÁWỌN Ọ̀DARÀN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 7, 2019

Ẹ RÌN JÌNNÀ SIPINLẸ OGUN LÁSÌKÒ ÀTI LẸ́YÌN ILÉYÁ - Ọ̀GÁ FIJILANTÉ PÀRỌWÀ FÁWỌN Ọ̀DARÀN

Béèyàn bá rí atẹjade ikilọ tí ọga àgbà Fijilante nipinlẹ Ogun, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Adedoyin fi síta laipẹ yi, yoo mọ pe ọkunrin naa ko gba igbakugba fun iwa ọdaran rara, paapaa bo tun ṣe sọ pe awọn ti da awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ko din ni ẹgbẹrun marun un sita kaakiri ipinlẹ Ogun lasiko ayẹyẹ ọdun Ileya to n bọ lọna yi.

Kọmanda Adedoyin sọ pe nitori pe aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lo jẹ wọn logun, eyi lo fa a, tawọn fi gbọdọ maa wa nimurasilẹ lati ṣe ojuṣe awọn ni gbogbo igba, paapaa lasiko ti ọdun ba ti n sunmọ etile, eyi tawọn adaran maa n fẹ ri gẹgẹ bi afaani lati ṣọṣẹ.

O fi ye wa ninu atẹjade naa pe kawọn ọdaran ti wọn ba lero pe awọn le ja baagi gba, tabi yọ foonu lapo awọn araalu, tabi lo gbajuẹ tete ba ara wọn sọrọ lati rin jinna sipinlẹ Ogun nitori pe gbogbo eto lo ti to.

Ọga agba naa to mọ daadaa nipa eto aabo, ẹni to tun ti gba oriṣiriṣi aami ẹyẹ ati iwe ẹri lori aabo naa tun jẹ ko di mimọ pe, asiko ẹlẹgẹ ti aabo ni orilẹede Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba wa bayii, idi ni yi to fi jẹ pe awọn ko gbọdọ foju kan oorun lọsan ati loru, to si jẹ pe awọn ẹrọ igbalode to n tu aṣiri ọdaran lo ti wa nilẹ ni sẹpẹ lati dẹkun awọn iwa ọdaran lawujọ.

Nibẹ lo tun ti jẹ ko ye wa pe ileeṣẹ awọn ko tii pinu lati fa sẹyin nipa fifọwọsowọpọ pẹluu awọn ileeṣẹ eleto aabo yoo ku bii Ọlọpaa, Sifu Difẹnsi atawọn ẹsọ oju popona kaakiri, nitori pe awọn ti forikori lati jẹ alaafia jọba lawujọ.

Bẹẹ lo tun fidi ẹ mulẹ pe kawọn ti wọn lero wipe awọn le ayẹyẹ awọn ọlọdun ru mọ pe ko ni i si aaye kankan fun wọn, nitori pe digbi lawọn ti mura silẹ, to si tun fi ye wa pe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn tawọn ko sita ni wọn ko ni wọ aṣọ idanimọ.

Nigba tó ń pàrọwà náà, ó sọ pé ọ̀daràn tí ọwọ bá tẹ yóò fi ẹnu rẹ fẹ ara bí abẹbẹ, kódà a, tó tún sọ pé àwọn tí wọn ba n rí, lẹ́yìn tó bá jaja bọ yóò bá a káàánú, tó sì ni ó ṣeé ṣe kí wọn fi ẹ̀wọ̀n gbára lábẹ́ òfin. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI