ỌWỌ TẸ AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN ONE MILION BOYS L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, August 19, 2019

ỌWỌ TẸ AWỌN ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN ONE MILION BOYS L'EKOO

Orin 'ọpẹ yẹ o Baba' lawọn eeyan mu sẹnu nipinlẹ Ekoo lana an, iyẹn nijọba ibilẹ Ọjọ, nigba tọwọ palaba awọn mẹjọ kan segi nibi ti wọn ti fẹẹ gbawọn eeyan wọle sinu ẹgbẹ okunkun.

Ojule kẹẹdogun, adugbo Alado, Shibiri lọwọ ti tẹ wọn nigba ti wọn sọ pe Yusuf Abu, ọmọ ogun ọdun lo fẹẹ gbawọn eeyan wọle sinu ẹgbẹ okunkun ti wọn pe ni One Milion Boys naa.


Awọn tọwọ tẹ naa ni Sunday Gabriel, ọmọ ogun ọdun; Rilwan Dauda, ọmọdun mejidinlogun; Mohammed Sikiru, ọmọdun mẹtalelogun; Ọladimeji Abayọmi, ọmọdun mejidinlogun; Rasheed Alabi, ọmọ ogun ọdun; Habeeb Idowu, ọmọdun mejidinlogun; Bisọla Ọlaiya, ọmọdun mejidinlogunati Hawawu Hazzan toun jẹ ọmọdun mọkandinlogun.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI