Ẹ WA RAN WA LORI ETO ẸKỌ NIPINLẸ OGUN - IJỌBA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, September 14, 2019

Ẹ WA RAN WA LORI ETO ẸKỌ NIPINLẸ OGUN - IJỌBA PARIWO SITA

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti rawọn ẹbẹ sawọn eeyan, paapaa awọn ajọ lagbaye lati wa a ran wọn lọwọ lori idagbasoke ati ilọsiwaju eto ẹkọ nipinlẹ naa, kawọn akẹkọọ wọn le kun oju oṣuwọn lati maa figagbaga pẹluu awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye. 
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele lo rawọ ẹbẹ naa laipẹ yi nibi ti wọn ti n fi ile oni kilaasi mẹrin kan lọlẹ, eyi ti ajọ kan ti wọn pe ni Build A School Initiative in Africa (BASIA) ṣagbatẹru ẹ nile ẹkọ St. Peter's College, Senior School, Olomore, Abẹokuta.
Nibẹ naa ni wọn tun ti fi yara igbọnsẹ to peregede, omi ẹrọ to ja geere ati ọfiisi awọn oṣiṣẹ (Staff Room) naa lọlẹ
Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele gbe oriyin fun ajọ naa fun ipinu ati igbesẹ lati mu idagbasoke bawọn ile ẹkọ, nibẹ lo si ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe owo kekere lo n gbe eto ẹkọ duro lasiko yi, to si ti ju agbara ijọba lọ.
Idi ni yii to fi sọ pe awọn ṣi nilo awọn oluranlọwọ, atawọn alagbatẹru ijọba bii ẹgbẹ awọn akẹkọọ (Alumni); ẹgbẹ awọn obi ati akẹkọọ lati ran wọn lọwọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI