ẸGBẸ AGBABỌỌLU ỌMỌ NAIJIRIA, ARLINGTON FC GBẸRẸGẸJIGẸ L'AMẸRIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, September 8, 2019

ẸGBẸ AGBABỌỌLU ỌMỌ NAIJIRIA, ARLINGTON FC GBẸRẸGẸJIGẸ L'AMẸRIKA


Bí wọn ba n sọ nípa ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù tó ń ṣe dáadáa julọ lásìkò yí nílẹ̀ Amẹ́ríkà lásìkò yí, kí wọn too bẹ̀rẹ̀ sii dárúkọ mẹ́wàá, kò ṣeé ṣe kí wọn má dárúkọ Arlington FC, to jẹ́ pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni. 

Ọdún tó kọjá tíì ṣe 2018 ni wọn fi egbe agbábọ̀ọ̀lù náà lélẹ̀, tí wọn sì ti bẹ̀rẹ̀ sii kópa nínú àwọn Liigi tí wọn ń gba nibẹ, tí wọn sì ń tayọ kọjá àfẹnusọ nípa fífi àgbà hàn àwọn akẹgbẹ́ wọn. 

Texas ni Arlington Dallas NI ẹgbẹ́  agbábọ̀ọ̀lù náà wa, tó sì ń lọ káàkiri láti gbé ògo àwọn ọmọ Nàìjíríà yọ. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìfẹ̀yìntì àwọn agbábọ̀ọ̀lù ni wọn ṣe dá ẹgbẹ́ náà silẹ, ṣùgbọ́n títayọ tí wọn ń tayọ lọ mú kí ìpinnu wọn fẹẹ máa yí padà báyìí, 

Ìfigagbága kan tó gbajúmọ̀ dáadáa, ìyẹn Major League Soccer TI won N da pé ní MLS, là gbọ́ pé àwọn ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù káàkiri tí ń mú àwọn tó dára julọ lásìkò yí, tí wọn sì làwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Arlington náà kò gbẹ́yìn nibẹ.


Àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọn ń tukọ ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù náà ni Ọ̀gbẹ́ni ṣèyí ṣówùnmí àti Ebenezer Fọwọ́bajé tí wọn jẹ gbajugbaja olokoowó lagbaye, tí wọn sì ń gbé wọn gẹgẹ nínú idije MLS, nítorí pé wọn kò lè fi wọn ṣeré. 

Àwọn akọ́ni-mọ̀n-gbá méjì nnì, Eric Daughty atu Deen la gbọ pé wọn jẹ igi lẹyin ọgbà fún ìgbéga wọn níbi idije UPSL tí ipele keji (Lower division 2, to the more competitive Division 1(UPSL).

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI