ỌDUN KAN LẸYIN IKU IYAWO KASNATY, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 8, 2019

ỌDUN KAN LẸYIN IKU IYAWO KASNATY, GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ L'ABẸOKUTA

Bí èrè, bí awada, bí àlá lóró náà sì ń rí lọ́kàn gbogbo àwọn tó mọ gbajumo sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nnì tó filuu Abeokuta sebugbe, Ogbeni Kolawole Adejojo látàrí bo se pàdánù ìyàwó ẹ, Oloogbe Alaaja Semiat Oyindamọla Adejojo lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù Kẹ̀sán án ọdún tó kọjá, ìyẹn 2018 ni nkan bí agogo mejo alẹ.

Image may contain: 2 people, including Kolawole Adejojo Kasnaty, people smiling, people standing and indoor 
Oni tii ṣe ọjọ kẹjọ oṣu kẹsan an lo pe ọdun kan gbako ti Alaaja Sẹmiat Adejojo ki aye pe o digboṣe.

Image may contain: 1 person, standing 
Ko pẹ ti iyawo Kasnaty to yan iṣẹ aṣaraloge laayo dagbere faye niroyin naa ti tẹ awọn to sunmọ ọn lọwọ, to si jẹ pe kaka kawọn kan gbagbọ, 'ko le ri bẹẹ, ko gbọdọ jẹ bẹẹ' ni wọn n sọ.

Image may contain: Kolawole Adejojo Kasnaty and Adejojo Zemmy'at Oyindamola, people smiling, people standing and indoor 
Ṣugbọn nigba tawọn to sunmọ ọkunrin naa bẹrẹ sii kii ku irọju lori ikanni ayelujara lo mu kawọn kan bẹrẹ sii gbagbọ, ti wọn si bẹrẹ sii fi atẹjiṣẹ ibanikẹdun ranṣẹ sii lori aago rẹ.

Image may contain: 2 people, people standing 
Aarọ ọjọ keji ni wọn pada sin Oloogbe Sẹmiat si itẹkuu kan niluu Abẹokuta.

Nnkan to jẹ ki iṣẹlẹ naa ṣe awọn eeyan ni kayeefi pupọ nigba naa ni pe ipalẹmọ ayẹyẹ ọjọ ibi Sẹmiat ni wọn n ṣe lọwọ, tori ta a gbọ pe ko ju bi ọsẹ kan si asiko ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni nnkan ti a n sọ yi ṣẹlẹ.

Image may contain: 2 people, including Adejojo Zemmy'at Oyindamola, people smiling, indoor 
Fawọn to ba mọ gbajugbaja sọrọsọrọ naa daadaa, wọn a mọ pe latigba tiṣẹlẹ naa ti waye, ko si igba tabi asiko kan ko ma ṣeranti iyawo, paapaa lori ikanni ayelujara ti facebook, ko da, ti wọn loo ṣi tun ranti lọjọ Fraide ijẹta, tawọn eeyan si ki ku arafẹraku titi dasiko yi.


Remembering Semiat: Eulogy for a Friend and wife, one year down the lane your memories lingers.
Oyindamola Semiat Adejojo, who died on 8th September, 2018.
How can I say good-bye to someone who has been an integral part of my life for over the years? 
...See More
Comments
Adura wa ni pe ki Ọlọrun fi ẹmi gigun ta ọkunrin naa lọrẹ, ati pe ki Ọlọrun bu ororo itura si ọkan rẹ. Bẹẹ la n gba a ladura pe ki Ọlọrun pese iyawo ti yoo ba a kalẹ fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI