AWỌN ARẸ AGBAYE N ṢE IDARO IKU ROBERT MUGABE, Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌBASANJỌ SỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 7, 2019

AWỌN ARẸ AGBAYE N ṢE IDARO IKU ROBERT MUGABE, Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌBASANJỌ SỌ

Laarọ kutu ọjọ Ẹti tii ṣe Fraide ana ni iroyin naa jade sita Aarẹ tẹlẹri l'orilẹ-ede Zimbabwe, Robert Mugabe ti jade laye. Kayeefi, ati pe lojiji niroyin iku naa ba gbogbo agbaye.

Ohun ta a gbọ ni pe ọsibitu kan lorilẹ-ede Singapore ni Robert Mugabe wa lati bi oṣu meloo kan sẹyin nibi to ti n gba itọju, latari aisan ọjọ ogbo ti wọn loo kọluu, to si jẹ pe nibẹ lo gba jade laye lẹni ọdun marundinlọgọrun (95years).

Lati ọdun 1980 lo ti n tukọ orilẹede Zimbabwe titi wọ ọdun 2017 nigba ti igbakeji rẹ yẹ aga mọ nidi pẹlu atilẹyin ileesẹ ologun. 

Adanu nla n'iku Rubert Mugabe jẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ

Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Oluṣegun Ọbasanjọ ti sọ pe, iku aarẹ Zimbabwe ana, Robert Mugabe jẹ adanu nla fun gbogbo ilẹ adulawọ lapapọ.  

O salaye pe Robert Mugabe jẹ ajijagbara ti o mọ pataki ki eeyan ja fun ominira.

Aare Obasanjọ wa kẹdun iku aarẹ ana ọhun, o si tun sọ pe yoo soro lati ri ẹni ti yoo lee di alafo ipo ti oloogbe naa dimu nilẹ adulawọ gẹgẹ ajijagbara.


"Mugabe fi ìgboyà dáábò bo ilẹ̀ Áfíríkà lọ́wọ́ ìmúnisìn

Baa ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye.

Awọn olori orilẹede Lagbaye ti n sedaro akẹẹgbẹ wọn, Robert Mugabe to siwọ isẹ ni aarọ ọjọ Ẹti.

Mugabe fi ara rẹ jin fun ironilagba ọrọ aje ati oselu - Aarẹ Naijiria

Nigba to n daro pẹlu orilẹede Zimbabwe lori ipapoda akọni asaaju naa, aarẹ ilẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ni oloogbe naa jẹ ajijagbara to ja fitafita fun ominira orilẹede ọhun, to si fi ọpọ igba aye rẹ sin ọmọniyan.

Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun eto iroyin rẹ, Fẹmi Adesina fisita, Buhari ni ọpọ ifiraẹnijin ti Mugabe se, paapa nidi ijijagbara fun ironilagbara awọn eeyan rẹ lẹka oselu ati ọrọ aje ni iran yii ati eyi to n bọ ko ni gbagbe laalae.

Buhari wa gbadura pe ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun akọni naa, ko si tun tu awọn ẹbi rẹ ninu lori isẹlẹ adanu nla yii.

Awujọ agbaye yoo maa ranti Mugabe gẹgẹ bii 'ẹni to ni igboya' - Aarẹ Kenya

Bakan naa ni aarẹ orilẹede Kenya ti se apejuwe Robert Mugabe gẹgẹ bii "agba awujọ, ajafun ominira orilẹede ati ololufẹ ilẹ adulawọ to se ojuse ti ko kere lati mu atunse ba ifẹ ilẹ adulawọ"

"A maa ranti aarẹ Mugabe gẹgẹ bii onigboya ẹda, ti kii bẹru lati ja fun ohunkohun to ba nigbagbọ ninu rẹ, koda araye koo baa lodi si ero naa."

Afirika ti padanu ọkan lara awọn akinkanju asaaju - Aarẹ Tanzania


Loju opo Twitter tiẹ, aarẹ orilẹede Tanzania, John Mugufuli ti sedaro lede Swahili pe "Ilẹ Afirika ti padanu ọkan lara awọn akinkanju asaaju, ẹni to tako iwa imunisin lati ipasẹ awọn igbesẹ rẹ."

Mugabe fi ẹmi aibẹru daabo bo ilẹ Afirika - Aarẹ Zambia

Ko tan sibẹ, aarẹ ilẹ Zambia Edgar Lungu naa ti kede pe "A maa ranti Mugabe fun bo se 'fi ẹmi aisibẹru daabo bo ilẹ Afirika'."

Loju opo Twitter rẹ, o ni "oludasilẹ orilẹede Zimbabwe ati ololufẹ ilẹ adulawọ" naa ni orukọ rẹ ko ni parẹ ninu itan ilẹ Afirika."

Àwọn 'ogún burúkú' tí Mugabe fi sílẹ̀ ṣì wà síbẹ̀ - Olóṣèlú alátakò

Ọpọ awọn eeyan lagbo oselu lorilẹede Zimbabwe, awọn olori orilẹede lagbaye ati awọn eekanlu lawujọ agbaye ti n sọ ohun ti wọn mọ nipa Robert Mugabe.

Eyi to ya ni lẹnu julọ ni bi awọn eeyan kan se n sọrọ ti ko tọ nipa oloogbe naa.

Akọwe fọrọ ilẹ okeere ni ilu Ọba, United Kindom, Emily Thornberry kede pe oun ko lee sun ẹkun kankan nitori pe Mugabe jade laye.

"O gba akoso orilẹede to si n se ọpọ ileri...sugbọn nigba to ya lo sina patapata, mo si ro pe o seranwọ lati ba anfaani ti orilẹede rẹ ni lọjọ iwaju lati de ibi giga jẹ."

'Mugabe kuro lati ajijagbara bọ si afiyajẹni'

Bakan naa ni akojọ iroyin kan ni Mugabe ba ọrọ aje awọn alawọ funfun jẹ ni orilẹede Zimbabwe nitori pe wọn ri ọwọ mu ni orilẹede ọlọra naa.

Iroyin naa n se ni iroyin ayọ gba gbogbo orilẹede Zimbabwe kan nigba ti wọn fi tipa yẹ aga mọ Mugabe nidi.

'Ogun buruku' ti Mugabe fi silẹ si wa sibẹ - Oloselu alatako

David Coltart tii se oloselu alatako latinu ẹgbẹ oselu MDC lorilẹede Zimbabwe ti kede pe gbogbo ọmọ orilẹede Zimbabwe ni ko ni gbagbe Mugabe nitori iwa ipa ati iwa ajẹbanu to fi silẹ nilẹ naa.

Coltart, ti Mugabe sọ ni suna 'ọta orilẹede' , ks soju opo Twitter rẹ pe wọn ko ni gbagbe oloogbe naa pe ko seese ki eeyan fi oju fo ọpọ asise oloogbe naa lasiko to wa lori oye.

Ọ̀pọ̀ ìtàn tí Robert Mugabe kọ nígbà ayé rẹ̀ rèé:

Nigba ti Robert Mugabe n se abẹmi loke eepẹ, o kọ oniruuru itan manigbagbe to kọja ero ẹda,

Bi o tilẹ jẹ pe ọmọ atapata dide ni Mugabe, ti baba rẹ si jẹ Kafinta, sibẹ ko jẹ ki igbe aye mẹkunnu yii di oun lọwọ lati de ibi giga laye.

Robert Mugabe, tii se olukọ ni ibẹrẹ pẹpẹ aye rẹ, ni oju rẹ ri mabo lọwọ awọn oyinbo amusin ko to di pe orilẹede Zimbabwe, taa mọ si Rodesia tẹlẹ, gba ominira.

Diẹ ree lara awọn koko ohun ti Mugabe gbe ile aye se:


  • 1924: Ọjọ ti a bi

  • Lẹyin e yi, o di olukọ
  • 1964: Ijọba orilẹede Rhode ju si ẹwọn
  • 1980: O bori ninu idibo to saaju ominira orilẹede naa
  • 1996: Mugabe fẹ iyawo rẹ, Grace Marufu
  • 2000: O kuna ninu idibo bẹẹni tabi bẹẹko, awọn ọmọ ogun rẹ (pro-Mugabe militias) se ikọlu si oko awọn eniyan alwọ funfun ati ẹgbẹ alatako lorilẹede naa
  • 2008: O se ipo keji ninu idibo to gbe Tsvangirai wọle ni ipele akọkọ, amo ti Tsvangirai so wi pe oun ko se mọ lẹyin ikọlu si awọn alatilẹyin rẹ
  • 2009: Mugabe bura wọle fun Tsvangirai gẹgẹ bi Olootu ilẹ naa laarin ọrọ aje to dẹnukọlẹ fun ọdun mẹrin
  • 2017: O kọwe lọ gbe ile rẹ fun Igbakeji rẹ,Emmerson Mnangagwa, eleyii to faye silẹ fun iyawo rẹ, Grace lati bọ si ipo
  • 2017 November: Ile-isẹ ologun fi ipa gba ipo lọwọ rẹ
  • 2019 September: Robert Mugabe dagbere fun aye pe o digbose.

"Robert Mugabe, a kò leè gbàgbé ìtàn rere tó kọ ní Zimbabwe"

Bi ọdẹ ba ku, ọdẹ naa lo n se oro lẹyin ọdẹ.

Ni kete ti iroyin iku aarẹ ana lorilẹede Zimbabwe gba orilẹede agbaye kan, ni ọpọ eeyan ti n se idaro iku rẹ.

Niwọn igba to si jẹ pe onikangun ni ikangun, aarẹ to wa lori oye lọwọ-lọwọ bayii, Emmerson Mnangagwa, lasiko to n kede iku ọga rẹ tẹlẹ naa fi tẹdun tẹdun sọ bi iku Mugabe ti kaa lara to.

Emmerson Mnangagwa, ẹni to daro loju opo Twitter rẹ salaye pe "akọni fun eto ijijagbara ati alawọ dudu to nifẹ ilẹ rẹ tọkan-tọkan ni Robert Mugabe nigba aye rẹ.

O ni Mugabe fi gbogbo aye rẹ ja fun ominira ati eto ironilagbara awọn eeyan rẹ ni, ti orilẹede Zimbabwe ati ilẹ Afirika lapapọ, ko si lee gbagbe ipa manigbagbe to ko ninu itan.

Bẹẹ ba gbagbe, Emmerson Mnangagwa lo fi tipa gba ipo aarẹ lọwọ Robert Mugabe pẹlu atilẹyin awọn ologun losu Kọkanla ọdun 2017.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI