Ẹ WO ỌMỌDUN MEJIDINLOGUN TO JI OWO ỌRẸ ATI IDAMẸWA NI ṢỌỌṢI L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 21, 2019

Ẹ WO ỌMỌDUN MEJIDINLOGUN TO JI OWO ỌRẸ ATI IDAMẸWA NI ṢỌỌṢI L'EKOO

Boroboro ni gendekunrin ọmọdun mejidinlogun kan, Elikor Ehud n ka nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo tẹ ẹ lori ẹsun ole jija ti wọn kan an. Ṣọọṣi ni Ehud ti lọọ ji owo naa, ti wọn lowo idamẹwa ati ọrẹ tawọn ọmọ ijọ da ni.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọgbọn ọjọ oṣu kẹjọ ọdun yi la gbọ pe Ehud lọ ṣọọṣi naa, to si lọọ fọ ibi ti wọn n ko owo si. Ko pẹsigba naa la gbọ pe Pasitọ ṣọọṣi naa ti wọn pe ni Divine Chosen Vine Ministry to wa lagbegbe Ejigbo niluu Eko ṣakiyesi pe awọn ole ti wa.

Loju ẹsẹ lo ti gba tẹsan ọlọpa lọ lati lọọ fi to wọn leti, nibi iwadi awọn ọlọpaa laṣiri Ehud ti tu pe oun lo ṣiṣẹ naa, idi ni yi ti wọn fi lọọ gbe. Loju ẹsẹ tawọn ọlọpaa ti muu lo ti bẹrẹ sii tu gbogbo aṣiri naa fun wọn wipe ki wọn ṣe oun jẹjẹ.

O tun jẹ ko ye awọn ọlọpaa wipe kii ṣe oun nikan loun ji owo naa to le ni idaji miliọnu naira diẹ, iyẹn 670,000 naira ko, awọn meji pere ni, to si ni Lucky lorukọ ẹni tawọn jọ ji owo naa ko.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati ri Lucky mu, taa si gbọ pe wọn yoo foju awọn mejeeji bale ẹjọ laipẹ, iyẹn bọwọ palaba Lucky ba ti segi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI