O PARI, WỌN JI IGBAKEJI KỌMIṢANA ỌLỌPAA GBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 21, 2019

O PARI, WỌN JI IGBAKEJI KỌMIṢANA ỌLỌPAA GBE

Titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan ni gbogbo ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ṣi fi n dẹgbẹ lati wa igbakeji Kọmiṣana ọlọpaa nipinlẹ Niger, ACP Musa Rambo tawọn ajinigbe ji gbe loju ọna Kaduna si Jos.

Ọjọ Satide Abamẹta ti a lo tan yi la gbọ pe wọn ji ọkunrin naa gbe, ta a si gbọ pe awọn ajinigbe naa ti n beere aadọta miliọnu naira lọwọ awọn ọlọpaa ki wọn to le yọnda ẹ fun wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna si ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ loooto ni, ati pe awọn ti n ṣiṣẹ tọsan-toru lati gba ACP Rambo silẹ lọwọ awọn ajinigbe naa, bo tilẹ jẹ pe ko sọ iye tawọn ajinigbe naa n beere lọwọ wọn, ṣugbọn ti a pada gbọ pe aadọta miliọnu (50million) naira lowo naa. 

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Yakubu Sabo fi sita, lo ti jẹ ko ye wa pe nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan niṣẹlẹ naa waye, nigba ti wọn lawọn ọlọpaa kegberegbe kan ṣalabapade mọto Rambo lẹgbẹ opopona, ti wọn si ba kaadi idanimọ rẹ nibẹ.

Ṣugbọn Kọmiṣana ọlọpaa, Ali Aji Janga ti fọkan awọn araalu balẹ pe laipẹ lawọn yoo ri ọkunrin naa gba lọwọ awọn ajinigbe yi, bẹẹ gbawọn eeyan lamọnran pe ki wọn ran awọn lọwọ nipa tita awọn lolobo, bi wọn ba kofiri awọn eeyan yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI