GBAJUMỌ OṢERE TIATA, SISI FẸRARI DUBULẸ AISAN, O NILO IRANLỌWỌ GIDI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, October 21, 2019

GBAJUMỌ OṢERE TIATA, SISI FẸRARI DUBULẸ AISAN, O NILO IRANLỌWỌ GIDI

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkan lara awọn gbajumọ oṣere tiata Yoruba lorilẹ-ede Naijiria, Mary Adufẹ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Sisi Fẹrari wa bayii, latari aisan to daa dubulẹ.

Aisan kan ti wọn lo maa n ṣe awọn obinrin, iyẹn Iju (Fibroid) la gbọ pe o da Sisi Fẹrari dubulẹ lati bi ọdun meloo kan sẹyin, ṣugbọn ti ko tete mọ, nigba to si maa fi ṣakiyesi, kinni naa ti wọọ lara gidi.

Gbajugbaja ni Sisi Fẹrari jẹ nidi iṣẹ tiata, yatọ si wipe o n ṣe tiata, o tun mọ nipa ijo jijo, to si tun niṣẹ min in to n ṣe. Ọpọlọ rẹ tun ji pepe ninu  ka kọ iwe jade, to si ti kọ oriṣiriṣi iwe jade.

Laipẹ yi ni Mary Adufẹ, iyẹn Sisi Fẹrari kọ iwe kan nipa awọn Ọjọgbọn lorilẹ-ede Naijiria, lati fi bu ọla ati iyi fun iṣẹ takun-takun ti wọn n ṣe lọwọlọwọ.

Ko pẹ ti Sisi Fẹrari ṣakiyesi aisan naa lara rẹ, lo gba ọsibitu lọ fun iṣẹ abẹ, bo tilẹ jẹ pe ko kọkọ fẹẹ ṣe, ṣugbọn gbara ti wọn loo ṣe iṣẹ abẹ naa tan, ṣe ni nnkan tun yiwọ fun un, ti ko si le ṣe bo ṣe n ṣe tẹlẹ mọ.

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu irora nla ni gbajumọ oṣere tiata naa wa, to si nilo iranlọwọ ẹyin ẹlẹyinju aanu lati ṣaanu ẹ. Ọpọlọpọ owo lo ti na lori aarẹ to n ṣe e yi, ṣugbọn ti ipa ti fẹẹ pin, idi ni yii to fi n beere fun iranlọwọ.

Ninu ọrọ rẹ "Mi o gbadun ara mi mọ latigba ti mo ti la iṣẹ abẹ naa kọja, mo si nilo iranlọwọ awọn eeyan lati le jẹ ki n gbadun, nitori pe mi o le ṣe awọn nnkan ti mo n ṣe tẹlẹ mọ. Latinu irora kan bọ si imin in ni mo wa bayii."

Lara awọn ti Sisi Fẹrari ṣẹṣẹ kọ itan lori wọn tan ni: Baba ati Mama Adeboye; Fẹmi Ọtẹdọla; Pasitọ Kalẹjaiye; Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu; Ṣade Tinubu; Adedeji Adeleke; Yẹmi Ṣolade; Ayọ Adesanya; Folukẹ Daramọla; Gomina Babajide Sanwo-Olu; Ọmọba Dapọ Abiọdun; Abiọdun Alabi; Mike Adenuga ati Ṣẹyẹ Kẹhinde, to si jẹ pe ipalẹmọ lati koo jade lo n ṣe lọwọ ki aisan naa too wọle sii lara.

Iwe naa re e
Lati ran an lọwọ, ẹ le pee sori nọmba ibanisọrọ rẹ: 08081360063. Ẹ si le fi owo ranṣẹ si apo ile ifowopamọ si rẹ
Account Name: Mary Adufẹ
Account Number: 0117585501
Bank: GTB.

Ọlọrun yoo wa pẹluu yin, aisan ko ni daa yin dubulẹ o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI