Ko sẹni ti ko rẹrin nile ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo lọjọ Fraide ana nigba ti baale ile ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan, Oluwatunbọsun Fadahunsi ti wọn fẹsun kan wipe o ṣeku pa iyawo rẹ, Funmilayọ n ka boroboro nile ẹjọ.
Baba arugbo naa sọ pe oun ko tete mọ pe iyawo oun lo wa lọwọ oun, toun n dunbu, nitori pe ẹran ewurẹ loun pe e, afigba toun pa a tan ni oju oun too ṣẹṣẹ la wipe iya awọn ọmọ oun ni.
Dahunsi ti wọn fẹsun ipaniyan kan la gbọ pe ọjọ karun un oṣu yi lo ki ada mọlẹ ni nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ, to si ṣa iyawo rẹ, Funmilayọ pa. Ita-Ipele camp to wa n'ijọba ibilẹ Ọwọ niṣẹlẹ naa ti waye.
Nigba to n sọrọ niwaju Onidajọ Charity Adeyanju, Dahunsi sọ pe "Mi ọ mọ idi ti mo fi mu ada lati maa ṣaa, ati pe nigba ti mo kọkọ fi ada naa ṣa, ko pariwo. Igba to to ya lo pariwo pe kawọn eeyan gba oun, ṣugbọn ṣe ni ohun ẹ dabi ti ẹwurẹ leti mi.
"Idi ni yii ti mo fi tẹsiwaju lati maa ṣaa, nitori pe ṣe lo dabi ẹni pe ẹwurẹ ni mo n ṣa lasiko naa, mi o mọ pe iyawo mi ni. Igba to ku tan ni oju mi ṣẹṣẹ la. Ẹru to ba mi lo jẹ ki n salọ. Ẹ jọwọ, ẹ foju aanu wo mi nitori pe bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ ko ye mi rara.
"Ọrọ owo ileewe awọn ọmọ wa la n ja si, kii si ṣe pe a n yọ ẹṣẹ si ara wa, mi o ti ẹ mọ pe mo ṣa a rara, igba to ku tan ni iye mi ṣẹṣẹ sọ, ti mo si salọ. Ẹ dariji mi, ki ẹ si ba mi bẹ awọn ọmọ mi."
Nigba toun naa n sọrọ, agbẹjọro fawọn ọlọpaa, Sulieman Abdulateef rawọ ẹbẹ si Onidajọ naa wi pe ko fawọn lanfaani lati ṣi fi Ọlatunbọsun pamọ si ọdọ wọn digba ti ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ifẹsunkan, iyẹn DPP yoo fi pari iṣẹ wọn.
Onidajọ naa wa a sun igbẹjọ min in siwaju di ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2020, to si ni ki wọn ṣi lọọ fi Ọlatunbọsun pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta titi igba naa.
No comments:
Post a Comment