FATAI ỌLALERE, AYEDERU BABALAWO TAWỌN EFCC MU NILUU IBADAN TI FOJU BALE ẸJỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, October 30, 2019

FATAI ỌLALERE, AYEDERU BABALAWO TAWỌN EFCC MU NILUU IBADAN TI FOJU BALE ẸJỌ O

Lọjọ Iṣẹgun (Tuside) ana ni ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo ilu kumọkumọ, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ fi oju Baale ile kan, Ọgbẹni Fatai Ọlalere Alli, ẹni tawọn eeyan mọ si Baba Abọrẹ ati Baba Ọṣun bale ẹjọ giga tijọba apapọ lori ẹsun jibiti.

O ti to bi oṣu meloo kan bayii ti awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti lọọ gbe Baba Abọrẹ nile ẹ, nibi tọwọ tun ti tẹ awọn oṣiṣẹ ẹ meji kan, Adigun Fatai Oluṣẹgun ati Olufẹmi Kọlawọle.

 
Gbogbo ẹsun ta a gbọ pe wọn ka si Baba Abọrẹ atawọn ọmọṣẹ ẹ yi lẹsẹ ni wọn lawọn ko jẹbi pẹluu alaye, ṣugbọn ti Onidajọ Patricia Ajoku to gbọ ẹjọ naa sọ pe kawọn oṣiṣẹ EFCC ṣi fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn digba ti igbẹjọ min in yoo waye lati mọ boya wọn lẹtọ si beeli atawọn afaani min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI