ỌWỌ TẸ AHMED TO N FIPA BAWỌN ỌMỌKUNRIN KEKEEKE LAṢEPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 30, 2019

ỌWỌ TẸ AHMED TO N FIPA BAWỌN ỌMỌKUNRIN KEKEEKE LAṢEPỌ

Kyeefi nla gba  a lọrọ baale ile ẹni ọdun marundinlogoji kan, Ahmed Isah ti wọn fẹsun kan wipe awọn ọmọdekunrin kekeeke tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹjọ si mẹwaa lọ laṣepọ nipinlẹ Niger.

Ọjọ Iṣẹgun (Tuside) ana ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa kede sita wipe aṣiri Ahmed ti tu wipe ko tii si ọmọdekunrin kan lagbegbe Ọja Tuntun to wa ni Sarkin-Pawa, iyẹn nijọba ibilẹ Munya ti ko tii ki kini abẹ ẹ bọ iho idi ẹ.

A gbọ pe ọjọ Abamẹta (Satide) to kọja yi ni wọn mu ẹsun Ahmed lọ fawọn ọlọpaa wipe ọmọ aburo rẹ lo ṣe kinni naa fun un, to si tun mu ọmọ min in wọle fun iru iwa bayii.

Ọpọ awọn la gbọ pe wọn tako Ahmed ni kete ti aṣiri rẹ tu wipe ko ṣẹṣẹ maa ṣe iru nnkan bẹẹ lati bi ọdun mẹta sẹyin, ṣugbọn tawọn ko tete fura.

Ohun ta a gbọ bayii ni pe ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI