GOMINA ABIỌDUN TUN ṢE BẸBẸ, Ó FUN AKẸKỌỌJADE FÁSÍTÌ CRESCENT TÓ PEREGEDE JULỌ NIṢẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, October 20, 2019

GOMINA ABIỌDUN TUN ṢE BẸBẸ, Ó FUN AKẸKỌỌJADE FÁSÍTÌ CRESCENT TÓ PEREGEDE JULỌ NIṢẸ


Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun tún ti kede igbanisiṣẹ akẹ́kọ̀ọ́ jáde kan, Abdulsalam Halimat Ibironkẹ niṣẹ lai kọ lẹ́tà ìwáṣẹ̀ rárá, àti pé yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ naa lẹ́yìn tó bá parí eto agunbanirọ rẹ. 

Igbakeji Gomina, Onímọ̀-ẹ̀rọ Nọimọt Salakọ-Oyedele lọ fìdí ẹ múlẹ̀ níbi eto ayẹyẹ ikẹkọọ jáde ti ilé ẹ̀kọ́ fasiti Crescent, ikọkànlá irú ẹ tó wà nílùú Abẹ́òkúta laipẹ yi. 

Nibẹ lo sì ti sọ pé Ìjọba ipinlẹ náà kò nii gbọjẹgẹ láti mú itẹsiwaju bá eto ẹ̀kọ́ nipinlẹ náà títí dìgbà tí yóò fi wà nipele tó yẹ kó wá ní amu pẹluu eto eko lagbaye, kò dá, táwọn ìlú yòókù yóò máa jowú.

Lára àwọn tó wà níbi ayẹyẹ náà ni Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Ọláyíwọlá Àtàndá Adéyẹmí; Aláké ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ; Ẹmir tiluu Kazaure nipinlẹ Jigawa, Alaaji Najib Hussaini Adamu àtàwọn min ín.

Ninu ọrọ oludasilẹ ilé ẹ̀kọ́ fasiti náà, Onidajọ-fẹyinti Bọlá Ajibọla dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó mú ayẹyẹ náà wáyé, bẹ́ẹ̀ lo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn dúró digbi pẹ̀lú ìfaradà wọn. 

Giwa ilé ẹ̀kọ́ náà, Ọjọ́gbọn Ibraheem Gbajabiamila gbáwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde náà lamọnran pé kí wọn lo ìrírí àti ẹ̀kọ́ wọn láti fi gbé ògo iléèwé wọn ga níbi yòówù tí wọn ba ti bá ara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI