VGN FUN ỌNỌREBU ISIAKA IBRAHIM LAWỌỌDU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, October 19, 2019

VGN FUN ỌNỌREBU ISIAKA IBRAHIM LAWỌỌDU


Ọga àgbà pátápátá fún ẹgbẹ́ fijilante lorilẹ-ede Nàìjíríà, Kọmanda Usman Muhammad Jahun tí fi aami ẹyẹ dá Ọnọrebu Isiaka Ibrahim tó ń ṣojú ẹkùn Ifo/Ewekoro nílé igbimọ aṣojú-ṣofin lọla látàrí àwọn ipa tó ń ko lágbègbè tó ń ṣojú. 

Ádárì ẹgbẹ́ náà nipinlẹ Ogun, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Nureni Adedoyin lo gbé aami ẹyẹ náà lè Ọnọrebu Isiaka lọwọ laarọ òní niluu Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ọgun. 

Nígbà tó ń gbé oriyin fún iṣẹ takuntakun tí ẹgbẹ́ náà ń ṣẹ lẹka eto ààbò lorilẹ-ede yí, ó lòun mọ pe bí ìjọba àpapọ̀ bá bù ọwọ lu ẹgbẹ́ náà, oun mọ pe eto ààbò tí dájú pelu idà ọgọrun. 

Nibẹ lo tí ṣèlérí wípé òun yóò sá gbogbo ipá òun láti ríi pé ìjọba Buhari tètè bù ọwọ lu ìwé abadofin náà ni kíákíá kí asiko too lọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI