ỌDAJU ABIYAMỌ FI INA JO ỌWỌ ỌMỌDUN MẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, October 30, 2019

ỌDAJU ABIYAMỌ FI INA JO ỌWỌ ỌMỌDUN MẸJỌ

Ko sẹni to ri ọwọ ọmọdekunrin kan tọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun mẹjọ lọ bo ṣe wu, ti ko maa ṣepe fun iyawo baba ẹ latari bo ṣe fi ina jo gbogbo ọwọ ẹ latari ẹsun ole jija to fi kan an.

 
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii mọ orukọ ọmọ naa ati iyawo baba rẹ dasiko ti a fi kọ iroyin yi tan, sibẹ, ohun ta a gbọ ni pe ipinlẹ Nasarawa lọhun niṣẹlẹ naa ti waye laarọ oni Ọjọru (Wẹside).

 
A gbọ pe ẹsun ole jija ni obinrin naa fi kan ọmọdekunrin yi, to si lọọ da ina igi, eyi to ki ọwọ ọmọ naa bọ titi to fi jona.

 
Ọpọ awọn to ri ọwọ ọmọ naa ni wọn n ṣepe rabandẹ loriṣiriṣi fun iyawo baba rẹ to ṣiṣẹ buruku yi fun un.

 
Awọ n ẹlẹyinju aanu ni wọn sare gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu nibi to ti n gba itọju di asiko yi, ta a si gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ obinrin naa. 
 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI