ỌWỌ TẸ GBAJUMỌ AAFA TÓ JI PÁTÁ ALABOYUN KA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, October 19, 2019

ỌWỌ TẸ GBAJUMỌ AAFA TÓ JI PÁTÁ ALABOYUN KA


"Ẹ fojú àánú wo mi, ẹ daṣọ àṣírí bo mi" lọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ tí wọn lo ń tẹnu gbajumọ Aafa kan tí a kò tíì mọ'rúkọ rẹ dasiko tí a ṣakojọpọ ìròyìn yí tán jáde lásìkò tọwọ palaba rẹ segi níbi tó ti lọọ jí pátá ká.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó gbé ìròyìn náà sì AWIKONKO létí laipẹ yi ṣe fi yẹ wá, ọjọ́ Fraide àná ni wọn lọ́wọ́ tẹ Aafa náà ni Fáṣítì Ibrahim Badamasi Babangida, èyí tó wà ní Lapai nipinlẹ Niger.


Wọn ní ọkùnrin yí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa jí pátá ká, tí wọn sì loo làwọn tó máa ń tà á fún, ṣùgbọ́n pátá alaboyun tó ji yí lo padà ṣàkóbá fún un.

A ti ẹ gbọ pé àwọn ọmọ Yahoo lo máa ń rán wọn niṣẹ burúkú yí, tó sì níye tí wọn máa ń fún wọn lórí pátá kan ṣoṣo. Lójú ẹsẹ tọwọ tí tẹ ẹ là gbọ pé wọn tí fà á lé àwọn agbofinro lọ́wọ́. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI