LẸ́YÌN ỌDÚN KẸSÀN-ÁN IKU Ẹ, KASNATY, GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢE ÌRÁNTÍ ALAASARI L'ỌJỌ MỌNDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 23, 2020

LẸ́YÌN ỌDÚN KẸSÀN-ÁN IKU Ẹ, KASNATY, GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ FẸẸ ṢE ÌRÁNTÍ ALAASARI L'ỌJỌ MỌNDE


Òní yìí gan-an ni gbajumọ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò àti tẹlifiṣan nnì, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo t'ọpọ àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ sì Kasnaty fẹẹ ṣe ìrántí ogbontarigi òṣeré tiata tó ti doloogbe, Iṣola Emmanuel Durojaiye, ẹni t’awọn eeyan tun mọ si Hammed Alaasari.

Aarọ ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun 2011 ni Hammed Alaasari jade laye n’ibi ijamba mọto to waye lagbegbe Onipẹpẹyẹ, nitosi Kọbapẹ to wa loju ọna Abẹokuta si Ṣagamu.

F’awọn to ba ranti daadaa, ibi ifilọlẹ fiimu ti oloogbe naa, iyẹn Alaasari fẹ ẹ gbe jade, eyi ti wọn pe ni Ọmọ Night Club ni ọkunrin naa n lọ ninu mọto to ṣẹṣẹ ra n’igba naa, iyẹn jiipu Nissan Armada pẹlu awọn mẹrin kan ki ijamba naa to o waye.

Oni yii ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2020 gan-an lo pe ọdun mẹsan-an gbako ti wọn sin Alaasari si ile ẹ to wa ni Ita-Ẹlẹga n'ilu Abẹokuta.

Aago mẹta ọsan ni Kasnaty fẹ ẹ ṣe iranti oloogbe naa lori eto rẹ to pe ni ‘Ko Maa Roll’ n’ileeṣẹ redio Splash 106.7FM to wa n’ilu Abẹokuta.
Awọn iyawo at'awọn ọmọ Alaasari nibi isinku ẹ
Oriṣiriṣi awọn aṣiri tẹnikẹni ko ti i gbọ nipa oloogbe naa la gbọ pe Kasnaty fẹ ẹ tu, t’awọn to si mọ oloogbe naa daadaa n’igba aye ẹ yoo tun sọ nnkan ti wọn mọ.

Ẹ ma gbagbe, aago mẹta ọsan oni ni eto naa yoo waye. Ẹ ku oju lọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI