O TAN O! WALE ADENUGA TU AṢIRI NLA N'IPA AWỌN OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 23, 2020

O TAN O! WALE ADENUGA TU AṢIRI NLA N'IPA AWỌN OṢERE TIATA

Iyalẹnu gba a ni aṣiri nla ti ogbontarigi onkọtan ati olugbe-fimmu-jade, iyẹn Purodusa (Producer) nni, Ọgbẹni Wale Adenuga tu nipa awọn gbajumọ oṣere oṣere tiata kaakiri orilẹ-ede Naijiria ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ.

Ilu Ibadan n'ipinlẹ Ọyọ ni Wale Adenuga to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pefti Films Institute to ti gbe ọpọ fiimu, paapaa sinima ọlọsẹ-ọsẹ jade ti tu aṣiri naa l'opin ọsẹ to kọja yii, to si ni oju aye ni pupọ wọn n ṣe, wọn ko ni owo kankan lọwọ.

Wale Adenuga sọ pe mama ati baba alaye (sugar mummies/sugar daddies) ni pupọ wọn fi n gbera nitori pe nnkan ko dan mọnran fun wọn.

Ọkunrin naa tun sọ pe pẹlu bi ijọba orilẹ-ede Naijiria ṣe n gbiyanju agbara wọn lati maa ya awọn oṣere tiata lowo lati fi maa fi gbe fiimu wọn jade, sibẹ, wọn ki i ri owo n'idi iṣẹ naa, eyi to n jẹ ki wọn maa tẹle awọn baba ati mama alaye kaakiri.

Bẹẹ lo tun fi kun un wi pe ki i ṣe ẹjọ wọn, bi ko ṣe pe oju t'awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ wọn fi n wo wọn gẹgẹ bi olowo lo jẹ ki wọn maa wa gbogbo ọna ti aṣiri wọn ko fi ni i tu sita wi pe wọn ko lowo lọwọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Pupọ ninu wọn lo jẹ pe baba alaye ati mama alaye ni wọn fi n gbe ara wọn. Ọpọ awọn eeyan ti wọn n ri awọn oṣere tiata ti wọn je aye familete ki n tutọ ni wọn ko mọ pe ki i ṣe idi iṣẹ tiata ni wọn ti n ri owo, bi ko ṣe pe ọna mi-in to ya patapata si iṣẹ tiata lo n pawo wọle fun wọn.

"Wọn maa n fẹ k'awọn eeyan lero wi pe idi iṣẹ tiata ni wọn ti n ri owo wọn, ati wi pe nnkan dan mọran fun wọn n'idi iṣẹ naa. Ẹ maa ri i wi pe wọn n kọ ile olowo nla, wọn jaye gidi, ṣugbọn ibi ti wọn ti n ri owo ju idi iṣẹ tiata lọ."

Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi wọn ko ṣe ni ẹgbẹ kan ṣoṣo ti gbogbo wọn sa si labẹ, to si ni ipo olori gan an lo n da wahala silẹ, ati pe awọn ẹgbẹ to wa ti wọn n ṣe, imọ-tara-ẹni ni wọn fi n ṣe e.

Pupọ awọn ọmọ Naijiria lọrọ naa le jẹ kayeefi l'oju wọn, ṣugbọn mo fẹ fi da a yin loju pe Nollywood nikan ni ẹgbẹ ti ko ni ẹgbẹ alajumọṣepọ ti yoo dari tabi mojuto ọrọ awọn oṣere at'awọn to n gbe fiimu jade.

B'awọn oniṣegun oyinbo ṣe n sọrọ nipa ẹgbẹ wọn, Nigerian Medical Association (NMA), l'awọn agbẹjọro naa n sọrọ nipa ẹgbẹ wọn, Nigerian Bar Association (NBA), bẹẹ oniroyin naa n sọ ti wọn, Nigerian Union of Journalists(NUJ).

"Otitọ ni wi pe Nollywood ni oriṣiriṣi ẹgbẹ, ṣugbọn imọ-tara-ẹni ni wọn fi n ṣe e. Ohun to daju ni pe aile korajọ jẹ ọkan pataki lara iṣoro to n doju kọ Nollywood, eyi ti ko jẹ ki wọn dagbasoke nipa okoowo ṣiṣe lorilẹ-ede Naijiria.

"Bi atunṣe ko ba tete wa, ajalu nla wa niwaju fun wọn. Ọpọ awọn ibi ti wọn ti n ṣe afihan fiimu lo jẹ pe ibi igbalode ti owo rẹ pọ ni, to si jẹ pupọ ni wọn ko le san owo iwọle sibẹ lati lọ wo fiimu. Ibi ti a nilo l'awọn ibi t'awọn ko lowo lọwọ ti le san ẹẹdẹgbẹta (500) naira lati wo fiimu.

"Bi Nollywood ba ṣe atunto daadaa, wọn maa ni anfaani si awọn nnkan bi owo ifẹyinti, eto ilera ọfẹ, eyi ti ko ri bẹẹ l'asiko yii. Onikaluku lo n da ọrọ ara rẹ gbe, t'awọn kabaa si n dagba"

Bakan naa lo tun sọ pe oun le darukọ awọn oṣere tiata ti wọn ti d'oloogbe nipa airi itọju to peye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI