ARẸWÀ ỌMỌGE GBÉ MAJELE JẸ NÍTORÍ OLÓLÙFẸ́ RẸ JA A JÙ SILẸ LÁSÌKÒ KONILEGBELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 6, 2020

ARẸWÀ ỌMỌGE GBÉ MAJELE JẸ NÍTORÍ OLÓLÙFẸ́ RẸ JA A JÙ SILẸ LÁSÌKÒ KONILEGBELE


Pupọ nínú àwọn tí wọn gbọ nípa ikú ọdọbinrin ẹni ọdún mẹtalelogun kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Rejioce lo ń ṣe ní kayeefi lórí bo ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ lọsan gangan lẹyin tí olólùfẹ́ rẹ tó gbé ara le ja a ju silẹ lójijì. 

Agbegbe Mpape tó wà n'ilu Abuja niṣẹlẹ̀ náà tí wáyé lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó fiṣẹlẹ náà tó AWIKONKO létí ṣe ṣàlàyé, wọn ní o ti pẹ tí Rejoice to jẹ́ ìyá ọlọmọ kan àti olólùfẹ́ rẹ náà tí ń bá ara wọn bọ tipẹ. 

Ṣádede ni wọn sọ pé olólùfẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ si í yí ìwà rẹ padà díẹ̀díẹ̀, tó sì má ń béèrè nnkan tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n tí olólùfẹ́ náà kò ní í sọ̀rọ̀.

Ko pẹ tí wọn ní àṣírí tú sí Rejoice lọ́wọ́ pé ọmọbìnrin mi-in ni olólùfẹ́ rẹ náà ń tẹle, tó sì tún ká wọn mọ ibi tí wọn tí ń ṣeré ìfẹ́. Wọn ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Rejoice tí bẹbẹ wí pé òun kò lè làjú silẹ kí obìnrin mi-ín gba ọkọ moun lọ́wọ́. 

A ti ẹ gbọ pé Rejoice tí fìgbà kan rí sọ fún olólùfẹ́ rẹ náà pe ṣe lòun yóò gbà ẹ̀mí ara òun ti ko ba dẹyin lẹ́yìn ọmọbìnrin náà. 

AWIKONKO gbọ pé látìgbà tí Rejoice tí bímọ fún ọkùnrin kan tí kò gbà oyun lọ́wọ́ rẹ lo tí ń da bùkátà ara rẹ pẹ̀lú ọmọ rẹ gbé, ìdùnnú ńlá lo sì jẹ fún un nígbà tó padà olólùfẹ́ rẹ tó já a ju silẹ yìí. 

Olólùfẹ́ náà là gbọ pé ó ń tọju Rejoice àti ọmọ rẹ nítorí ainiṣè lọ́wọ́. Nígbà tí wọn ní Rejoice kò rí iranlọwọ mọ, pàápàá lásìkò òfin konilegbele yìí ló mú kó pinu láti gba ẹmi ara rẹ, èyí ló fà á tí wọn lo ó fi ra oogun apẹfọn, tó sì gbé e mú. 

Ariwo ìrora to ń jẹ lo tá sì ara ti wọn jọ ń gbé ilé kan náà létí, tí wọn sì tètè gbé e lọ sí ọsibitu fún ìtọ́jú, ṣùgbọ́n tí ẹpa kò boro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI