ỌGA FIJILANTE TU AṢIRI ÀWỌN AMOOKUṢEKA SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 6, 2020

ỌGA FIJILANTE TU AṢIRI ÀWỌN AMOOKUṢEKA SITA


Ọga àgbà ẹgbẹ́ fijilante nipinlẹ Ogun, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin lo tí tú àṣírí táwọn èèyàn tún ń lo lásìkò yìí láti fi ṣiṣẹ ibi, tó sì ni irun àwọn obìnrin ni wọn ń lo ju báyìí.

Àárọ̀ òní tí í ṣe Mọnde ni Kọmanda Adedoyin tú àṣírí náà síta nínú atẹjade tó fi ranṣẹ sì AWIKONKO, tó sì laṣiri àwọn èèyàn náà tí ń tú sí wọn lọ́wọ́.

Adedoyin sọ pé káwọn èèyàn máa ṣe sún asunpaara tàbí gbàgbé ara wọn lórí nnkan ti ko kan wọn, kí wọn sì gbajumọ ọ̀rọ̀ ara wọn, pàápàá lásìkò konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí. 

O ni ọjọ́ Àìkú Sande àná lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ wọn tẹ afurasi ọ̀daràn kan n'ilu Abẹ́òkúta pẹ̀lú irun orí àwọn obìnrin.

O jẹ kò ye wá pé kò sí nnkan méjì tí wọn ń lo irun orí náà fún, bí kò ṣe oògùn owó, tí wọn a sì gbà aisiiki àwọn tó ní irun náà. 

Adedoyin ni káwọn obìnrin tó ń ṣe irun má ṣe fi irun wọn silẹ lọdọ àwọn aṣerunloge, ìyẹn hairdresser, nítorí pé nínú wọn tí ń tà irun náà fáwọn babaláwo láti lo ó fún nnkan ètùtù owó. 

Afurasi ọ̀daràn tọwọ tẹ náà ni Kọmanda Adedoyin tí ṣàlàyé pé ó jẹwọ fáwọn wí pé òun máa ń rà irun aloku lọ́wọ́ àwọn aṣerunloge n'ilu Abẹ́òkúta, tí yóò sì tà á fáwọn babaláwo. 

Bẹ ẹ lo wá gbawọn èèyàn lamọran wí pé tí wọn ba kẹẹfin afurasi ọ̀daràn lágbègbè wọn, kí wọn tètè fi tó ileeṣẹ wọn létí, tàbí kí wọn pé nọ́mbà tí ẹ ń wo yìí. 08167091852.

Bákan náà lo tún rọ àwọn aráàlú wí pé kí wọn rí í dájú pé ń tẹle àwọn òfin ìlànà konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí, kí wọn sì máa fọ ọwọ wọn loore koore láti dẹkùn itankalẹ aarun àṣekupani tí Coronavirus. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI