KAYEEFI! ÀṢÍRÍ BÍ ALAGA ÌJỌBA IBILẸ EJIGBO ṢE KÙ S'OGBOMỌṢỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 6, 2020

KAYEEFI! ÀṢÍRÍ BÍ ALAGA ÌJỌBA IBILẸ EJIGBO ṢE KÙ S'OGBOMỌṢỌ


Ṣé ni ariwo ibanujẹ tún sọ lẹgbẹ òṣèlú APC nipinlẹ Ọṣun lónìí ọjọ́ Aje, ìyẹn Mọnde pẹ̀lú bí alaga ìjọba ìbílẹ̀ Ejigbo n'ipinlẹ náà, Ọnọrebu Gbenga Ayegbayọ ṣe gba ekuru jẹ́ lọ́wọ́ ẹbọra

Ọsibitu aladani kan tó wà n'ilu Ogbomọṣọ, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ là gbọ pé Ọnọrebu Gbenga Ayegbayọ kú sí lónìí.

AWIKONKO gbọ pé àìsàn kan ló ń bá gbajumọ Ọnọrebu náà fúnra láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn, tó sì padà gba ẹ̀mí rẹ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́jú. 

Ọdún 2018 là gbọ́ pé wọn yàn Ọnọrebu yìí, tí wọn sì làwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ dáadáa. 

Fáwọn to bá mọ bí nnkan ṣe ń lọ dáadáa, pàápàá lásìkò tí Aarun àṣekupani tí Coronavirus yìí wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọn a mọ pe ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn ni ìròyìn nípa ilu Ejigbo yìí tí ń káàkiri.

Idi ni pé àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹtadinlaadoje (127) tí wọn ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ivory-Coast de sipinlẹ Ọṣun, tó sì jẹ pe agbegbe kan ńìjọba ìbílẹ̀ Ejigbo yìí ni wọn tọju wọn sì láti yẹ wọn wò bóyá wọn kò ní aarun Coronavirus, tó sì jẹ pe .

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI