Ẹ WO OJÚ ỌLỌPAA TO LU OLÓLÙFẸ́ RẸ DÁKÚ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, April 6, 2020

Ẹ WO OJÚ ỌLỌPAA TO LU OLÓLÙFẸ́ RẸ DÁKÚ L'EKOO


Bàwọn èèyàn ṣe ń ronú lórí ọ̀nà àbáyọ sì igbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí láti dẹkùn itankalẹ aarun àṣekupani tí Coronavirus, ọkùnrin ọlọpaa kan, Gbadebọ Adekunle Jacob lo tí lu olólùfẹ́ rẹ ń'ìlùkulù, tó sì tún ń halẹ wí pé kò ṣeni lè foun ṣe ohunkóhun.

Òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí là gbọ pé Adekunle tó wà l'ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Tolu tí Ajegunlẹ, ìyẹn Area B n'ilu Eko lu olólùfẹ́ rẹ náà lalubami. 


Wọn ní ṣe ni Adekunle lu ọlọmọge náà, tó sì jẹ pe díẹ̀ lo kú kò dákú, ṣùgbọ́n táwọn araadugbo doola ẹ̀mí rẹ. Inú agbára ẹ̀jẹ̀ là gbọ pé wọn tí gbé ọlọmọge náà kúrò, tí wọn sì tọju rẹ. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ní kí í ṣe àkọ́kọ́ re e tí Adekunle yóò máa lu olólùfẹ́ tí wọn tí jọ wá tipẹ náà, tí wọn sì ni ṣe ló máa ń mú mọra, ṣùgbọ́n èyí tó ṣe gbẹyin yìí ni wọn lo ó yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu. 

Ọlọmọge náà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sọ pé Adekunle tí sọ òun di baagi afẹṣẹkubiojo olojoojumọ, to jẹ pe ṣe lòun ń mú un mọra, àti pé lílu náà tí sú òun ló jẹ́ koun sọ̀rọ̀ jáde, káwọn èèyàn lè gbà òun. 


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Eko, Balla Elkana kò ti I dá esi atẹjiṣẹ wá padà lati fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ títí tá a fi kò ìròyìn yìí jọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI