WÀHÁLÀ DE! WỌN RÍ KORONAFAIRỌS LÁRA AMỌTẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, April 6, 2020

WÀHÁLÀ DE! WỌN RÍ KORONAFAIRỌS LÁRA AMỌTẸKUN


Àwọn aláṣẹ l'ẹka eto iṣẹ agbẹ àti ọ̀gbìn nilẹ Amẹ́ríkà tí sọ pé ayẹwo kan tí wọn ṣe lára ohun ọ̀sìn nnì, Amọtẹkun tí wọn ń pè ní Tiger tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé ẹranko náà ni aarun àṣekupani tí Coronavirus tó ń jà káàkiri àgbáyé. 

Amọtẹkun náà tí wọn ní ọgbà àwọn ẹranko tí Bronx Zoo tó wà n'ilu New York lo wa ni wọn ti sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣọgba lo kò aaru náà rán Amọtẹkun yìí. 

Amọtẹkun náà tí wọn fún lórúkọ Nadia là gbọ pé oríṣiríṣi àwọn èèyàn ló ti ń wo láti ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù tó kọjá. Lójijì ni wọn lo ó dubulẹ àìsàn, tí wọn sì ṣàyẹ̀wò Koronafairọs fún tí, ayẹwo náà lo fi ye wọn pé aarun náà wá lára rẹ gidigidi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI