FUNKẸ AKINDELE BU SẸKUN NI KỌỌTU, Ó N'IṢẸ ÈṢÙ NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 6, 2020

FUNKẸ AKINDELE BU SẸKUN NI KỌỌTU, Ó N'IṢẸ ÈṢÙ NI


Lónìí ní ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Eko fi ojú gbajumọ oṣerebinrin nnì, Funkẹ Akin délé-Bello tí ọ̀pọ̀ mọ sì Jẹnifa àti ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello t'awọn èèyàn tún ń pè ní JJC Skills bá ilé-ẹjọ Majisireeti to wá lágbègbè Ọgbà n'ilu Eko.
Omijé ń pè omijé rán niṣẹ nigbati Funkẹ bẹ̀rẹ̀ si í sunkún bí egbere lórí bo ṣe tàpá sì òfin konilegbele tijọba ṣe fáwọn aráàlú. 
Opin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí là gbọ́ pé Funkẹ, ìyẹn ìyá ìbejì tàpá sì òfin konilegbele t'ijọba ìpínlẹ̀ Eko gbé jáde. 
Ana ni ọwọ ọlọpaa tẹ Funkẹ àti ọkọ rẹ, tí wọn sì kó wọn lọ sí teṣan kò tó o di pé wọn fojú wọn ba ile-ẹjọ lónìí.
Ohun tí dájú ni pé bí ile-ẹjọ náà bá fi rí ẹri aridaju, ó ṣeé ṣe kí Funkẹ àti ọkọ rẹ fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹta gbáko gbàrà, tàbí kí wọn san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun náírà gẹgẹ bí owó ìtanràn sì ẹṣẹ wọn.

Attorney Jẹnẹra tilu Eko lo fẹ̀sùn kan t'ọkọ tiyawo náà níwájú Onidajọ Aje Afunwa, táwọn méjèèjì sì gba wí pé lóòótọ́ láwọn jẹbi ẹ̀sùn náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI