WỌN JÙ FUNKẸ AKINDELE ATI ỌKỌ RẸ S'ẸWỌN ỌJỌ́ MẸ́RINLA GBÁKO, LO BÁ Ń SUNKÚN BÍ EGBERE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 6, 2020

WỌN JÙ FUNKẸ AKINDELE ATI ỌKỌ RẸ S'ẸWỌN ỌJỌ́ MẸ́RINLA GBÁKO, LO BÁ Ń SUNKÚN BÍ EGBERE


Ọrọ náà yàtọ̀ sí fíìmù àgbéléwò pátápátá nílé ẹjọ́ Majisireeti tó wà ní Ọgbà, n'ilu Eko nígbà tí gbajugbaja oṣerebinrin nnì, Funkẹ Akindele bù sẹkun lẹ́yìn tí adajọ ju òun àti ọkọ rẹ, Rasheed Bello sì ẹwọn ọjọ mẹ́rìnlá gbáko pẹlu iṣẹ àṣekára. 

Òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní Funke Akindele pé apejẹ láti bá ọkọ rẹ ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí lai mọ pe wàhálà ńlá lòun fà sí ara rẹ lọ́run.

Onidajọ Aje Afunwa sọ pé kí Funkẹ àti ọkọ rẹ lọ ọ ṣíṣẹ ọlọjọ mẹ́rinla gbáko sìn ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn tún san owó ìtanràn bí wọn ṣe lòdì sí òfin konilegbe. 

Bẹẹ lo tún pàṣẹ wí pé kí wọn fi àwọn méjèèjì sábẹ́ ayẹwo láti mọ bọya wọn ní aarun àṣekupani Coronavirus láàrin asiko náà. 

Bákan náà lo tún sọ pé Funkẹ gbọdọ kọ orúkọ àti ẹ̀rọ ibanisọrọ gbogbo àwọn tó wà níbi apejẹ naa, kò sì mú wa sílè ẹjọ́. 

Ṣáájú asiko yii ni ileeṣẹ ọlọpaa tí sọ pé àwọn ṣí ń wá gbajumọ olorin nnì, Naira Marley àtàwọn tí wọn na pápá bora, nítorí pé gbogbo wọn ni wọn yóò gbà idajọ wọn lábẹ́ òfin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI