AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌGỌ́TA ỌDÚN, ÀTI AYAJỌ ỌDÚN KAN IGBAJỌBA! DAPỌ ABIỌDUN TÍ ÀWỌN ṢỌỌBU PA L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 29, 2020

AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌGỌ́TA ỌDÚN, ÀTI AYAJỌ ỌDÚN KAN IGBAJỌBA! DAPỌ ABIỌDUN TÍ ÀWỌN ṢỌỌBU PA L'ABẸOKUTA


Ìyàlẹ́nu l'ọrọ náà ṣì ń jẹ fún òpọ àwọn tó gbọ nípa bí ìjọba ipinlẹ Ogun, lábẹ́ Gómìnà Dapọ Abiọdun ṣe tí àwọn ṣọọbu pá n'ilu Abẹ́òkúta.

Agbègbè Ìsàlẹ̀-Igbein tó wà n'ilu Abẹ́òkúta làwọn ṣọọbu tí a gbọ pé ìjọba tí pá náà wà.

F'awọn to bá mọ, ìjọba àná lábẹ́ Ibikunle Amosun lo kọ àwọn ṣọọbu ìgbàlódé yìí fún irọrun aráàlú, tí wọn sì làwọn tó wà ní ṣọọbu yìí gbà fọọmu, kò too di pé wọn bẹ̀rẹ̀ sii lo wọn. 


Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà là gbọ àwọn èèyàn san fún owó fọọmu tí wọn fi gba ṣọọbu kan, kò too di pé wọn bẹ̀rẹ̀ sii san owó ṣọọbu náà diẹdiẹ.

Laarọ òní là gbọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, ẹ̀ka tó ń mojuto ọ̀rọ̀ ilegbe {Housing} dìde láti lọọ tí àwọn ṣọọbu náà pá.

Ohun tó ń jẹ ki ọ̀rọ̀ náà máa yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu ni bí wọn ṣe sọ pé òní tó jẹ́ ayajọ ọjọ́ òṣèlú awaarawa, tó sì tún jẹ́ ayajọ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún ẹ nijọba gbé igbesẹ yìí.

AWIKONKO gbọ pé ìjọba kò fu àwọn èèyàn yìí lára kò yóò di pé wọn lọ tí àwọn ṣọọbu náà pá, àti pé wọn kò sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ wí pé àwọn èèyàn yìí yóò tún owó san kò tó di pé wọn lọọ tí àwọn ṣọọbu náà pá. Òjìji ni wọn loo bá wọn. 

Lára àwọn tó ní ṣọọbu nílé itaja ìgbàlódé yìí tí wọn ba AWIKONKO sọ̀rọ̀ laipẹ yìí sọ pé ìjọba ni afi káwọn tún owó san, kò too di pé wọn bẹ̀rẹ̀ sii lo ṣọọbu náà padà.

Àwọn èèyàn náà tí wọn kò fẹ́ ká dárúkọ wọn jẹ kò ye wá pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà làwọn san nígbà ìjọba Amosun, táwọn sì tún ti ń san nínú owó ṣọọbu náà gangan. 

Wọn ní ṣàdédé nijọba tún de laarọ yìí, wí pé afi káwọn tún owó náà san lai mọ ìdí pàtàkì. 

"Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà ni wọn san pé ká kọ́kọ́ fi gba fọọmu. Lẹ́yìn èyí ni wón sọ pé ẹnikọọkan yóò san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún {N100,000} naira kí wọn too ṣí ṣọọbu náà fún wa."


Gbogbo akitiyan láti bá alaga ṣọọbu ìgbàlódé yìí sọ̀rọ̀ lo ja si pàbó lásìkò tá a ṣakojọpọ ìròyìn yìí tán. Wọn ní alaga náà àtàwọn oloye rẹ tí lọ sile Iyalode Ẹ̀gbá, Oloye Arábìnrin Alaba Lawson láti fi ọ̀rọ̀ náà too létí.

Bẹẹ là kò tíì rí àwọn alakoso ẹ̀ka ileeṣẹ ìjọba tó ń rí sì ọrọ ilegbe {Housing} sọ̀rọ̀ bákan náà. 

A fi ń dáa yín lójú pé bí a bá ti báwọn sọ̀rọ̀, a máa jẹ ki ẹ gbọ ohun tí wọn ba wa sọ. Ẹ kú ojulọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI