Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara tí ṣàpèjúwe abẹnugọn ilé igbimọ aṣofin ipinlẹ náà, Ọnọrebu Salihu Yakubu-Danladi gẹ́gẹ́ bí olufọkansin, onirẹlẹ àti akíkanjú ọkùnrin.
Àpèjúwe yìí wáyé láti fi mọ rírí ipa tí Ọnọrebu Yakubu-Danladi ń kó nínú ìdàgbàsókè àti òfin ipinlẹ fún tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún marundinlogoji {35year} to n ṣe lónìí.
Ninu ìtàn ipinlẹ náà, Ọnọrebu Salihu Yakubu-Danladi ni abẹnugọn ilé igbimọ aṣofin to kéré julọ, tó sì ń darí ilé igbimọ náà pẹ̀lú ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye látìgbà tó ti dé ipò náà.
O ni ọmọluabi gidi ni Ọnọrebu naa jẹ f'awọn to n ṣoju, to si tun jẹ iwuri nla lati nii ninu ijọba oun.
Abdulrazaq sọ pe ninu iṣakoso Yakubu-Danladi nile igbimọ aṣofin, o ti fi han daju pe ọmọluabi to ṣee fi ẹyin silẹ fun ni, ati pe ọna to n fi ṣakoso ti n mu ki iṣọkan, afojusun ati ọkan akikanju dagbasoke sii.
No comments:
Post a Comment