ỌBASANJỌ D'AWỌN OṢIṢẸ ABẸ RẸ DURO NITORI AIRI OWO OṢU SAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 31, 2020

ỌBASANJỌ D'AWỌN OṢIṢẸ ABẸ RẸ DURO NITORI AIRI OWO OṢU SAN


Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti jawe lọọ gbele ẹ f'awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nile ikawe rẹ, iyẹn OOPL to wa nilu Abẹokuta.

Ninu lẹta idaduro ti wọn fun ọkan lara awọn oṣiṣẹ naa, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe idaduro naa ko ṣẹyin ifasẹyin to ba eto ọrọ aje inu ọgba naa lasiko ajakalẹ arun koronafairọọsi.

A gbọ pe o ti pẹ ti Baba naa ti n jẹ awọn oṣiṣẹ rẹ lowo oṣu, ti wọn si ni fikan-san-kan ni wọn n fi owo oṣu naa ṣe.

Wọn ni ẹẹkan laarin oṣu mẹta si mẹrin l'awọn oṣiṣẹ yii n gba owo oṣu wọn, ti wọn si ni oṣu kinni ọdun yii l'awọn eeyan naa ti gba owo oṣu gbẹyin, to si jẹ pe idaji owo oṣu ni wọn gba ninu oṣu kẹrin ọdun yii, eyi ti won gba l'ogunjọ oṣu kẹrin.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI