BUHARI WA LATI JALÈ, KÓ PA, KÒ SÌ TÚN PARUN - FANI-KAYỌDE JÙ BỌMBU Ọ̀RỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 31, 2020

BUHARI WA LATI JALÈ, KÓ PA, KÒ SÌ TÚN PARUN - FANI-KAYỌDE JÙ BỌMBU Ọ̀RỌ̀


Minisita tẹlẹri f'ọrọ ọkọ ofururfu loirlẹ-ede Naijiria, Ọgbẹni Fẹmi fani-Kayọde ti sọ pe ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari ko yatọ si ọrọ Satani, to si ni Aarẹ Buhari ko ni ipinu meji bi ko ṣe lati jale, paayan ati lati fi nnkan ṣofo danu.

Fani-Kayọde lo sọrọ naa laipẹ yii nigba to n tako ọrọ ti agbẹnusọ Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina sọ sita laipẹ yii.

O ni latigba ti Aarẹ Buhari ti de l'ọdun 2015 lo ti sọ orilẹ-ede yii sinu okunkun biribiri.
Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina sọ pe "Igbajọba Buhari l'ọdun 2015 lo gba Naijiria silẹ lóko iparun".

Bẹẹ lo tun sọ pe koko mẹta pataki ni Aarẹ Buahri nipinu lati ṣe, awon naa ni eto aabo, gbigba eto ọrọ aje silẹ loko iparun ati gbigbogun ti iwa ajẹbanu.

Adeṣina wa a fi kun ọrọ rẹ pe awon aṣeyọri ijọba Buhari l'ọdun marun sẹyin ko ṣee figagbaga pẹlu awọn nnkan to jogun ba.

N'igba to n sọrọ, Fani-Kayọde sọ pe "Buhari wa lati ji, pa, ko si tun parun"
O ni lati bi ọdun marun-un ti Aarẹ Buhari ti gba ijọba, ko si nnkan pataki kankan to ṣe, bi ko ṣe pe o sọ orilẹ-ede yii sinu okunkun nla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI