ANGẸLI IMỌTOTO FẸẸ WỌ KWARA L'ỌJỌ SATIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 26, 2020

ANGẸLI IMỌTOTO FẸẸ WỌ KWARA L'ỌJỌ SATIDE


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede wi pe konilegbele lati tun ile ati ayika wọn ṣe.

Loni ni atẹjade naa jade sita wi pe ko saaye fẹnikẹni lati rin regberegbe kaakiri ipinlẹ naa lai jẹ pe o n ṣe atunṣe ayika ati agbegbe rẹ.

Amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina lori ọrọ agbegbe, Kayọde Oyin-Zubair lo f'ọrọ naa sita pe ko ni si ijade sita l'ọjọ Abamẹta, iyẹn Satide ọla.

O ni eto aabo ati igbaye-gbadun araalu lo jẹ ijọba ipinlẹ naa logun, eyi to fi pọn dandan f'awọn eeyan lati lo anfaani naa tun ayika wọn ṣe.

Oyin-Zubair gb'awọn alaga agbegbe lamọran wi pe ki wọn ri i daju pe wọn ṣe abojuto awọn eeyan lagbegbe wọn lati tun ayika ṣe.

AWIKONKO gbọ pe awọn alaga at'awọn oloye agbegbe ati igberiko ni yoo bẹrẹ si i kabuku bi agbegbe wọn ba n dọti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI