IDAGBASOKE ETO-ẸKỌ NI KWARA! AWỌN AKẸKỌỌJADE GBE ORIYIN FUN GOMINA ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 14, 2020

IDAGBASOKE ETO-ẸKỌ NI KWARA! AWỌN AKẸKỌỌJADE GBE ORIYIN FUN GOMINA ABDULRAZAQ

Awọn akẹkọọjade ileewe girama t'ilu Ilọrin, iyẹn Ilorin Grammar School ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori idagbasoke alaragbayida to n mu ba eto-ẹkọ n'ipinlẹ naa.

Laipẹ yii l'awọn igbimọ awọn akẹkọọjade, iyẹn Old Students n'ile-ẹkọ naa fi imọ-riri wọn han si Gomina AbdulRazaq lori bo ṣe tun awọn kilaasi to ti dẹnukọlẹ kaakiri inu ọgba ile-ẹkọ naa ṣe.

Ile-ẹkọ girama Ilọrin la gbọ pe o wa lara awọn ile-ẹkọ ọgbọn t'ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe lori wọn, ti wọn si ti fẹẹ pari bayii.

Ọna lati jẹ ki eto-ẹkọ wa ni irọrun f'awọn akẹkọọ, ati ọna lati jẹ káwọn ọmọ ti wọn ko si nile-ẹkọ pada n'ijọba dawọle yii.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI