O MA ṢE O! IJAMBA MỌTO TUN F'ẸMI EEYAN ṢOFO DANU L'ABULE-ẸGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

O MA ṢE O! IJAMBA MỌTO TUN F'ẸMI EEYAN ṢOFO DANU L'ABULE-ẸGBA


'Ẹ ba wa gbe e, ko tii ku' l'ariwo iranlọwọ t'awọn ara agbegbe Abule-Ẹgba niluu Eko n pa l'ọjọ Aje, iyẹn Mọnde ana, nigba ti tirela nla kan gba awakọ bọọsi, ti si jẹ pe l'oju ẹsẹ ni awakọ bọọsi naa ti ku.

Ohun ti a gbọ ni pe tirela nla naa ni ijanu rẹ ja danu lojiji lori ere, ti wọn si ni gbogbo akitiyan ẹni to wa a lo ja si pabo, idi ree to fi lọọ kọlu mọto bọọsi to n lọ jẹjẹ rẹ, tiyẹn naa si tun lọ kọlu tirela mi-in to rọra n rin niwaju rẹ.

Loju ẹsẹ la gbọ pe awakọ bọọsi naa ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, to si dero ọrun.

 
A tiẹ gbọ pe awọn to wa lagbegbe naa sare lọ sibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ lati doola ẹmi awakọ bọọsi yii, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ nigba ti wọn yoo fi de'bẹ.

Diẹ ree lara awọn fọtọ ijamba naa, ki Ọlọrun ma jẹ ka rin lọjọ ti ebi n pa ọna. Amin.

 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI