WAHALA APC! ỌṢHIỌMHỌLẸ LOUN TI GBA KAMU, BẸẸ LO NI ỌNA ABAYỌ TUNTUN LOUN N WA BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 18, 2020

WAHALA APC! ỌṢHIỌMHỌLẸ LOUN TI GBA KAMU, BẸẸ LO NI ỌNA ABAYỌ TUNTUN LOUN N WA BAYII


Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti ile-ẹjọ da duro laipẹ yii, Adams Ọṣhiọmhọlẹ tisọ pe oun ti gba kamu lori idajọ to waye lati da oun duro gẹgẹ bi alaga, ṣugbọn ṣa, o loun tun ti bẹrẹ sii wa ọna abayọ miran bayii.


Lori ẹrọ amohunmaworan ti ileeṣẹ Channels ni Ọṣhiọmhọlẹ ti sọrọ yii l'Ọjọru, Wẹside ana.

Ọṣhiọmhọlẹ l'oun yoo b'awọn agbẹjọro oun sọrọ lati jiroro lori igbesẹ t'awọn yoo tun gbe nitori pe oun ko le la oju silẹ ki nnkan maa lọ bayii.

O ni ile-ẹjọ nikan naa lohun kan ṣoṣo t'oun gbjule fun idajọ ododo, to si ni ọkan lara awọn to n bọwọ fun ofin orilẹ-ede yii loun jẹ.
  
Ṣaaju asiko yii ni igbimọ amuṣẹṣe ninu ẹgbẹ naa yan Gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi lati jẹ alaga fidihẹ, ṣugbọn ti wọn ni igbakeji rẹ,Ọmọba Hilliard Eta ni yoo gba iṣẹ rẹ ṣe nitori ilera rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI