ADANU NLA N'IKU AROTILE JẸ FUN NAIJIRIA - GOMINA ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 17, 2020

ADANU NLA N'IKU AROTILE JẸ FUN NAIJIRIA - GOMINA ABDULRAZAQ


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq l'ọjọ Tọside ana ti kanminu lori iku ọdọbinrin awakọ ọkọ ologun ti ofurufu akọkọ l'orilẹ-ede Naijiria (Nigerian Air Force first female combat pilot), Tolulọpẹ Arotile to d'oloogbe laipẹ yii, to si ṣapeju iku ẹ gẹgẹ bi adanu nla.

Arotile la gbọ pe o dagbere f'aye nibi ijamba ọkọ ofurufu ti ologun naa, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe opopona ti ko dara lo ṣokunfa ijamba to sọ ọ di ero ọrun alakeji.

O ni asiko to yẹ ki orilẹ-ede maa gbadun ọmọbinrin naa n'iku mu-un lọ, eyi tolo o ba ni lọkan jẹ gidi.

Gomina AbdulRazaq wa a ba gbogbo awọn ọmọ ogun ti ofurufu k'ẹdun iku ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI