GOMINA ABDULRAZAQ KỌ LẸTA SI AJỌ EFCC LATI WA TỌPINPIN BI IPINLẸ KWARA ṢE N NA OWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 15, 2020

GOMINA ABDULRAZAQ KỌ LẸTA SI AJỌ EFCC LATI WA TỌPINPIN BI IPINLẸ KWARA ṢE N NA OWO


Lati le jẹ k'awọn araalu mọ pe wọn ko dibo fun gbajuẹ tabi gomina olojukokoro, Gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq ti kọwe si ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC lati wa a tọpinpin bi wọn ṣe n na awọn owo to n wọle, ati eyi ti wọn n gba lọwọ ijọba apapọ, iyẹn allocations.

Gomina Abdulrazaq ni ipe toun n pe ajọ EFCC ni lati wa a ṣe agbeyẹwo bi awọn owo ti wọn n gba lọwọ ijọba apapọ, paapaa eyi ti wọn pin f'awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ Kwara laaarin ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun-un si asiko yii.

AbdulRazaq loun ko ni nnkan ikọkọ toun yoo maa bo, to si loun ni ẹri ọkan to maa n jẹ koun ranti atubọtan lasiko toun ba fẹẹ gbe igbesẹ to ṣee ṣe ko ba orukọ oun jẹ.

O ni ki i ṣe ajọ EFCC nikan loun n pe lati wa a tọpinpin bi awọn owo tijọba apapọ n pin f'awọn ijọba ibilẹ ṣe n lọ, bi ko ṣe igbimọ olutọpinpin ni ẹka yoowu, ki wọn si tu aṣiri awọn to ba na owo ninakuna sita fun gbogbo agbaye.

AWIKONKO gbọ pe ki i ṣe pe Gomina AbdulRazaq dee de pe ajọ EFCC, bi ko ṣe lori awuyewuye ti wọn l'awọn kan n gbe kaakiri wi pe wọn n dari ọọdunrun miliọnu (300m) naira kuro ninu owo to jẹ t'awọn ijọba ibilẹ, eyi ti wọn gba lọwọ ijọba apapọ loṣooṣu.

Yatọ si eyi, Gomina AbdulRazaq tun loun rọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati jiroro lori ọrọ naa, ki wọn si sọ abajade rẹ sita.

O loun nígbagbọ wi pe o yẹ k'ijọbaibilẹ le da owo ti wọn n gba na funra wọn lai jẹ pe ijọba ipinlẹ tabi ẹni yoowu da si gẹgẹ bi ofin ti la a kalẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI