Ẹ WO OJU IGBAKEJI GOMINA AKEREDOLU TUNTUN, LẸYIN TI AARIN OUN ATI IGBAKEJI RẸ TẸLẸ, AJAYI DARU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 29, 2020

Ẹ WO OJU IGBAKEJI GOMINA AKEREDOLU TUNTUN, LẸYIN TI AARIN OUN ATI IGBAKEJI RẸ TẸLẸ, AJAYI DARU


Gómìnà ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Rotimi Akeredolu loni Ọjọru tí kéde Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa gẹ́gẹ́ bí igbakeji rẹ tuntun níbi idibo tó ń bọ̀ lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún yìí. 

Níbi tí wọn tí búra fún kọmiṣanna tuntun, Idowu Ọtẹtubi ni ọ̀rọ̀ náà tí jade, ìyẹn n'ilu Akurẹ tó jẹ́ olú-ìlú ìpínlẹ̀ Òndó. 

Ayedatiwa to jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ igbimọ ìdàgbàsókè Niger Delta, ìyẹn Niger Delta Development Commission tẹlẹri lo wa lati ìjọba ìbílẹ̀ Ilajẹ. 

Gómìnà Akeredolu sọ pé òun ti gbé Ayedatiwa yẹwo fínnífínní, tòun sì rí í pé ó peregede fún ipò náà, èyí tó mú koun fẹẹ lo ó gẹ́gẹ́ bí igbakeji. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI