Ọga àgbà ileeṣẹ fijilante, ó VGN n'ipinlẹ Ogun, Kọmanda Ọlanrewaju Nureni Adedoyin tí sọ pé kò sí ibẹru fẹnikẹni lásìkò pọpọṣinṣin ọdún Ileya tó wà níta yìí.
Adedoyin sọ pé gbogbo eto lo tí tó pátápátá nípa eto ààbò tó péye fáwọn aráàlú, tó sì ni àwọn òṣìṣẹ́ wọn tí wá níta rẹpẹtẹ láti dáàbò bo àwọn èèyàn.
Kọmanda Adedoyin lo sọ̀rọ̀ náà nínú atẹjade tó fi síta laarọ òní, èyí tó fi ń kí àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò ìpínlẹ̀ náà kú ayẹyẹ ọdún Ileya.
Ọkùnrin tó kọṣẹmọṣẹ nípa eto ààbò, tó sì tún ti gba oríṣiríṣi àmì ẹyẹ káàkiri Nàìjíríà àti àgbáyé náà sọ pé idanilẹkọọ tó péye làwọn òṣìṣẹ́ wọn tí gbà lórí ọ̀nà láti dẹkun àwọn oniṣẹ ibi.
Adedoyin tẹsiwaju pé àsìkò yìí làwọn oníwà búburú máa ń lo àǹfààní ẹ láti ṣiṣẹ́ ibi, tó sì làwọn tí gbaradi fún wọn láti kápá gbogbo wọn.
Ó wàá gbawọn èèyàn lamọran lati ṣe ọdún wọn nínú ilé wọn lai fòyà pẹ̀lú ìlànà àti òfin ìjọba lojuna láti dẹkun ìtànkálẹ̀ ajakalẹ àrùn Covid-19.
No comments:
Post a Comment