WỌN TI RI NỌỌSI TO POORA L'EKOO, OTẸẸLI NIBI TO TI N GBATẸGUN NI WỌN TI RI I - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 15, 2020

WỌN TI RI NỌỌSI TO POORA L'EKOO, OTẸẸLI NIBI TO TI N GBATẸGUN NI WỌN TI RI I

Bo ṣe jẹ pe orin ọpẹ l'awọn mọlẹbi, ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ Ayọmide Adetọla Alao kọ lasiko yii, bẹẹ ni ọrọ bi wọn ṣe pada ri i ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ pe wọn n wa a.

Otẹẹli kan to wa ni Ipetumodu-Okoku n'ipinlẹ Ọṣun la gbọ pe wọn ti pada ri Ayọmide Alao lẹyin ọjọ mẹrinla ti wọn loo ti jade nile.

Ibiṣẹ ni wọn sọ pe Ayọmide dagbere, ti wọn lo n ṣiṣẹ nọọsi ni ọsibitu FMC to wa ni Ebute-Mẹta, ipinlẹ Eko n lọ laarọn ọjọ naa, ṣugbọn ti ko pada sile, atigba naa la gbọ pe wọn ti n wa a.

Aburo rẹ, Ọlabunmi la gbọ pe o lọ fi ọrọ ẹgbọn rẹ to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si bẹrẹ si i wa a. N'ibi ti wọn l'awọn ọlọpaa ti n ṣiṣẹ ofintoto wọn la gbọ pe wọn ti ṣalabapade ẹ ni otẹẹli kan, nibi to ti n ṣe faaji ara rẹ.

Lara awọn to fi bi wọn ṣe ri Ayọmide to awọn oniroyin leti ni wọn sọ pe ọmọge naa ko le ṣalaye bo ṣe de otẹẹli naa. Wọn loo sọ pe oun mọ pe oun jade nile lati lọ sibiṣẹ laarọn ọjọ toun poora.

Ṣadede lo sọ pe n'igba toun maa fi mọ ibi toun wa, ọjọ ti lọ, toun ko si le sọ pe ilu bayii loun wa titi di asiko ti wọn ri i.

Gbogbo bi wọn ṣe n pe Ayọmide lori foonu ni ko gbe latigba naa, bo tilẹ jẹ pe foonu rẹ ko ku.

Awọn alabojuto otẹẹli meji ọtọọtọ ti wọn ni Ayọmide de si ni wọn sọ pe ko sẹni to tẹle e lẹyin debẹ, t'awọn ko si le sọ pato nnkan to gbe e debẹ, ati pe awọn ko ri i gẹgẹ bi ẹni ti nnkan n ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI