GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ BA IGBAKEJI RẸ, KÁYỌ̀DÉ ALABI YỌ̀ L'ORI AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌDÚN MẸ́TÀDÍNLỌ́GỌ́TA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 1, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ BA IGBAKEJI RẸ, KÁYỌ̀DÉ ALABI YỌ̀ L'ORI AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ỌDÚN MẸ́TÀDÍNLỌ́GỌ́TA


Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí ìpínlẹ̀ Kwara tí bá igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi yọ lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tó ń ṣe lónìí, ọjọ́ Kínní oṣù kẹjọ ọdún 2020.

Ninu ọ̀rọ̀ ikinni náà tó fi ranṣẹ sì Alabi lọsan òní, tó sì tún gbé e sórí ìkànnì ayélujára Twitter ni Gómìnà AbdulRazaq ni ṣàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bí èèyàn jẹjẹ pẹ̀lú ọkàn akíkanjú tó sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun. 

Ó ní Alabi jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ń fẹ́ ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú àṣeyọrí ìjọba wọn. 

Bẹ́ẹ̀ lo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run túbọ̀ máa bukun ẹ láti lè jọ gbé ìpínlẹ̀ náà lárugẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI