ILEEṢẸ NTA TO JONA NI KWARA! IJỌBA ṢELERI LATI TUN UN ṢE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 19, 2020

ILEEṢẸ NTA TO JONA NI KWARA! IJỌBA ṢELERI LATI TUN UN ṢE


L'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ṣeleri fun awọn alakoso ileeṣẹ tẹlifiṣan orilẹ-ede Naijiria nni, National Telivision Authority, NTA n'ipinlẹ naa pe oun yoo ri i daju pe awọn ṣe atunkọ ileeṣẹ naa leyi ti yoo dun un wo loju.

Ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ina deede ṣẹyọ ni ileeṣẹ tẹlifiṣan naa, to si jo apa kan ọfiisi nibẹ.

Nibẹ ni Gomina ti sọ pe ipa ti ileeṣẹ tẹlifiṣan naa ko laye awọn eeyan nipa awọb eto wọn ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Maa sọ fun Kọmiṣanna fun ọrọ akanṣe iṣẹ lati ṣe akọsilẹ awọn nnkan ti wọn padanu, a maa ṣagbatẹru ẹ gẹgẹ bi a ti maa n ṣe e."

AbdulRazaq sọrọ yii lasiko ti ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan naa, Ibn Muhammed ṣe abẹwo si i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI