OJULOWO OOGUN IBILẸ DI OHUN AGBEGẸGẸ NI KWARA, IJỌBA T'ỌWỌ BỌ'WE ADEHUN PẸLU ILEEṢẸ NIPRD - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 19, 2020

OJULOWO OOGUN IBILẸ DI OHUN AGBEGẸGẸ NI KWARA, IJỌBA T'ỌWỌ BỌ'WE ADEHUN PẸLU ILEEṢẸ NIPRD


Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati t'ọwọ bọ'we adehun pẹlu ileeṣẹ National Institute for Pharmaceutical Research and Development (NIPRD) lori pipese awọn oogun ibilẹ ti yoo wo oriṣiriṣi aisan ati arun.

Nibi eto idanilẹkọọ ọlọjọ mẹta ti ileeṣẹ NIPRD naa ṣe agbatẹru rẹ ni Gomina AbdulRazaq ti yan ọrọ yii leti awọn eeyan pe oogun ibilẹ (Traditional Medicine) ṣe pataki, paapaa lawujọ.

Idanilẹkọọ yii la gbọ pe wọn ṣagbekalẹ ẹ lati sọ pataki idi t'awọn ọjọgbọn lẹka eto ilera ibilẹ yo fi maa ṣe awọn oogun ibilẹ to jẹ ojulowo.
 
Nibẹ ni Gomina ti gbe oṣuba kare fun agbarijọ awọn oniṣegun {Pharmaceutical body) lori idanilẹkọọ naa, to si ni o ti ko ipa ribiribi lẹka eto ilera.
 
O ni ijọba oun yoo ri daju pe oun n gbe ṣiṣe ojulowo oogun ibilẹ larugẹ n'ipinlẹ Kwara ati pe ijọba ti ṣetan lati ni ajọṣepọ to peye peye pẹlu ileeṣẹ lojuna lati jẹ ki ojulowo ipese oogun ibilẹ di ohun agbegẹgẹ ki eto ilera le tubọ kẹsẹjari.
 
Bakan naa lo tun pe akiyesi awọn eleto ilera si oogun 'Nigerian Formula' ti yoo dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun Covid-19, eyi ti yoo jẹ ipinlẹ Kwara ni yoo ti kọkọ jade bi i ti orilẹ-ede Madagascar.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI