Gẹgẹ bi Aṣaoye tilu Ikọgọsi, Oloye Ayọ Ademilua ṣe fi to awọn akọroyin leti, o ni amuwa Ọlọrun ni, ti ki i si i ṣe pe ẹnikẹni lo ran ara naa s'awọn maluu yii.
Oloye Ademilua ni iru nnkan bẹẹ ko ṣẹlẹ ri lagbegbe ọhun, to si lo n jẹ kayeefi f'oun at'awọn araalu, ati pe ojiji n'iṣẹlẹ naa b'awọn. Oun lo si jẹ ko ye wa pe itosi odo Ikọgọsi to wa loju ọna Ipole-Ekiti n'iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ.
O tun jẹ ko di mimọ pe awọn Fulani to l'awọn maluu naa ni wọn fi to awọn eeyan to n kọja lọ leti wi pe ara lo san pa maluu awọn, ko to di pe iroyin naa jade sita.
Onikọgọsi tilu Ikọgọsi Ekiti, Ọba Abiọdun Ọlọrunniṣọla ninu ọrọ tiẹ lo ti fẹsun kan awọn Fulani naa wi pe wọn n gbero lati ta oku awọn maluu naa f'awọn araalu lati jẹ, eyi to lo o sọ pe ewu nla ni beeyan fifẹnukan maluu ti ara ba san pa.
No comments:
Post a Comment