AWỌN NNKAN TI Ẹ KO MỌ NIPA JIMỌH ALIU, AGBA OṢERE TIATA TO KU, ATI BO ṢE KU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 18, 2020

AWỌN NNKAN TI Ẹ KO MỌ NIPA JIMỌH ALIU, AGBA OṢERE TIATA TO KU, ATI BO ṢE KU


Ibanijẹ iku Alaaji Yẹkinni Oyedele t'awọn eeyan tun n pe ni Baba Lẹgba lo ṣi wa lọkan awọn eeyan, ti ko si ti i tan nilẹ ko to o di pe iroyin iku agba ọja oṣere tiata mi in naa tun gba igboro kan, to si n ṣe awọn eeyan ni kayeefi.

Oni ni wọn yoo sinku Oloye Jimọh Aliu toun naa tun dagbere f'aye l'Ọjọbọ, Tọside ana lẹni ọgọrin ọdun l'ọsan ana, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Iwadii fi ye wa pe laipẹ yii ni wọn ṣẹṣẹ pari lokeṣan fiimu kan, eyi ti wọn pinnu lati fi ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọdun karundinlaadọrin, nibẹ gan-an ni wọn sọ pe ara wọn ko ti ya, ti wọn ni wọn ko le sọrọ daadaa.

Ṣugbọn awọn to sunmọ wọn to ba wa sọrọ sọ pe ara wọn ti n balẹ, ko to di pe ọrọ naa yiwọ, to si mu ẹmi agba oṣere ọhun lọ. Ọpọ awọn oṣere tiata ti wọn jọ wa ni lokeṣan ni ọrọ iku yii si n jẹ kayefi fun pe ṣe iṣẹ aṣegbẹyin ti Baba naa fẹẹ ṣe reee.

Ọla, ọjọ Abamẹta, ni wọn yoo sinku Oloye Jimọh Aliu si Okemẹsi gẹgẹ bi ilana ti Oloogbe naa ti la silẹ ko to ku pe ẹgbẹ Baba oun ni ki wọn sin  oun si, bẹẹ la gbọ pe adura ọjọ mẹjọ yoo waye ni Ado-Ekiti.

DÍẸ̀ LÁRA OHUN TÓ YẸ KÍ Ẹ MỌ̀ NÍPA OLÓYÈ JÍMỌ̀ ÀLÍÙ
Ọjọ́ kọkànlá, oṣù kọkànlá ọdún 1939(11/11/1939) làgbà òṣèré yìí dáyé. Ọmọ bíbí ìlú Òkè-ìmẹ̀sí ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì ni.
 
Aláwo tó mọfá yánrán ni Alàgbà Fákọ̀yà Àlíù tó jẹ́ Bàbá Olóyè Jímọ̀. Ọmọ ìlú Ìloro-Èkìtì ni ìyá rẹ̀.
 
Ọdún 1959 ni ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Akin Ògúngbè tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gbajúgbajà nígbà náà, ó sì lo ọdún méje lábẹ́ ọ̀gá rẹ̀ kí ó tó dá ẹgbẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 1966 tó pè ní “Jimoh Aliu Concert Party” ìlú Ìkàré ní Ìpínlẹ̀ Ondo ni wọ́n kalẹ̀ sí nígbà náà.
 
Ó darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Ológun ní ọdún 1967 tí ó sì fẹ̀yìntì lọ́dún 1975. Láti ọdún 1975 ni ó sì ti gbájú mọ́ eré ṣíṣe, nínú èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣèré tó lórúkọ ti gba abẹ́ ìtọ́ni rẹ̀ kọjá nínú ẹgbẹ́ tó pè ní “Jimoh Aliu Cultural Group” Lára àwọn eré tí wọ́n ti ṣe ni;
 
👉 Ikú jàre Ẹ̀dá
👉 Yánpọnyánrin
👉 Fọ́pomọ́yọ̀
👉 Àjálù
👉 Àrélù
👉 Ìrìnkèrindò
👉 Rúkèrúdò abbl
 
Àgbà òṣèré yìí pajúdé ní òní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàn-án, ọdún 2020 (17/9/2020).
 
Kí Olódùmarè ó má jẹ̀ẹ́ kí gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ ó bàjẹ́.
Èwo nínú iṣẹ́ Bàbá yìí ni ẹ̀yin ò leè gbàgbé?No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI