ẸGBẸ OṢELU APC ṢE IPADE ỌTẸ LE ṢEYI MAKINDE LORI L'ỌYỌ, WỌN PINNU AWỌN ỌNA TI WỌN YOO FI LEE DANU L'ỌDUN 2023 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 17, 2020

ẸGBẸ OṢELU APC ṢE IPADE ỌTẸ LE ṢEYI MAKINDE LORI L'ỌYỌ, WỌN PINNU AWỌN ỌNA TI WỌN YOO FI LEE DANU L'ỌDUN 2023


Loni ni ẹgbẹ alatako n'ipinlẹ Ọyọ, All Progressives Congress ṣe ipade alaafia laarin ara wọn, nibi ti wọn ti panupọ lati fimọ ṣọkan lori ọna ti wọn yoo gba yọ Gomina Ṣeyi Makinde l'ọdun 2023.

F'awọn ti ko ba mọ, lati nnkan bi ọdun meloo kan sẹyin ni ẹgbẹ naa ti pin, t'awọn agbaagba at'awọn ọmọlẹyin ẹgbẹ oṣelu naa ko si gba itọ ara wọn da mi, ṣugbọn ni bayi, awọn eeyan naa ti sọ pe alaafia ti jọba.

Nibi ipade naa ni alaga ileeṣẹ eto ikansira-ẹni (NCC) lorilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Adeolu Akande; minisita tẹlẹ fọrọ eto ikansira-ẹni, Amofin Adebayọ Shittu; Sẹnetọ Sọji Akanbi; Sẹnetọ Ayọ Adeṣeun ati Alaaji Abu Gbadamọsi to jẹ alaga ipade naa ti sọ pe eṣu ti pofo laarin wọn.

Lara awọn to tun wa nibi ipade naa ni Oloye Goke Oyetunji, Amofin Niyi Akintọla; Alaaji Fatai Ibikunle; Ọnọrebu Saheed Fijabi Ọnọrebu Bọsun Ọladele ati Ọnọrebu Sunbọ Olugbemi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI