COVID-19: UBEC ṢE IDANILẸKỌỌ F'AWỌN OLUKỌ AGBA NI KWARA, WỌN TUN GBA WỌN LAMỌRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 17, 2020

COVID-19: UBEC ṢE IDANILẸKỌỌ F'AWỌN OLUKỌ AGBA NI KWARA, WỌN TUN GBA WỌN LAMỌRAN


Kọmiṣanna fun eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan (Education and Human Capital Development), Hajia Fatimah Bisọla Ahmẹd ti gba gbogbo awọn alakoso ile-ẹkọ girama kekere ati agba patapata n'ipinlẹ naa lamọran wi pe ki wọn tẹle awọn ilana lati dẹkun itankalẹ arun Koronafairọọsi gẹgẹ bi alakalẹ ajọ NCDC to n ri sọrọ ajakalẹ arun lorilẹ-ede Naijiria.
 
Eyi waye nibamu pẹlu b'awọn ile-ẹkọ ṣe fẹẹ pada sẹnu ẹkọ wọn.

Kọmiṣanna naa ti akọwe agba ẹka eto ẹkọ, Arabinrin Kẹmi Adeọṣun ṣoju fun lo sọrọ naa nibi idanilẹkọọ ti wọn ṣe f'awọn alabojuto ile ẹkọ girama at'awọn olukọ agba, eyi ti ajọ UBEC ati KWSUBEB ṣagbatẹru ẹ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe ojuṣe gbogbo eeyan, paapaa awọn olukọ ni lati tẹle ilana ti arun naa ko fi ni i pọ si i.
 
"A ni lati ri i daju pe a n tẹle awọn ilana ti ajọ NCDC ati ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ lorilẹ-ede yii gbe kalẹ bi i fifọ ọwọ, jijina sira ẹni, lilo ibomu, lilo ifọwọ at'awọn mi in."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI