ÈYÍ TÚN GA Ò! KWARA FẸẸ ṢE ÀTÚNṢE ILÉ Ẹ̀KỌ́ TÓ LÈ NÍ ẸGBẸ̀RÚN KAN, LÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BA N FO F'ÁYỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 8, 2020

ÈYÍ TÚN GA Ò! KWARA FẸẸ ṢE ÀTÚNṢE ILÉ Ẹ̀KỌ́ TÓ LÈ NÍ ẸGBẸ̀RÚN KAN, LÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BA N FO F'ÁYỌ̀


Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó lè ní ẹgbẹ̀rún kan nijọba ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí ṣe ìlérí wí pé òhun yóò ṣe atunkọ wọn, tí gbogbo rẹ yóò sì wà nibamu lọ́nà ìgbàlódé.

Ọjọ́ Ajé, Mọnde àná ni Gomina AbdulRazaq sọ̀rọ̀ náà síta nílùú Ajaṣẹ-Ipo tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Kwara South, níbi apero eto iṣuna ọdún 2021 wí pé eto ẹ̀kọ́ gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí ti ìgbàlódé ń'ìpínlẹ̀ náà. 

Nibẹ lo tí sọ pé ipò tí pupọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ káàkiri ìpínlẹ̀ náà wá kò bójúmu rárá, tó sì lo ó kú díẹ̀ kaato pẹ̀lú ipò tí eto ẹ̀kọ́ wá lagbaye lónìí. 

I ni ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ àwọn àtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà díẹ̀-díẹ̀, kí wọn sì fi àwọn irinṣẹ íkẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́. 

AbdulRazaq jẹ́ kó di mimọ pé kí í ṣe atunkọ àwọn kíláàsì ni wọn ń pè ní ilé ẹ̀kọ́ gidi, bí kò ṣe àwọn irinṣẹ àti eto ìlànà ẹ̀kọ́ àgbáyé ni wọn fi ń dá ògidì ilé ẹ̀kọ́ tó pé ojú owó, tó sì lòun ṣetan láti ṣe é. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI