KO SẸNI TÓ LÈ T'ỌWỌ BỌ́ ỌPỌLỌ ÀWỌN ỌMỌ ÀTI OLÙGBÉ ÌPÍNLẸ̀ KWARA - YINKA FAFOLUYI PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 8, 2020

KO SẸNI TÓ LÈ T'ỌWỌ BỌ́ ỌPỌLỌ ÀWỌN ỌMỌ ÀTI OLÙGBÉ ÌPÍNLẸ̀ KWARA - YINKA FAFOLUYI PARIWO SÍTA


Oludamọran àgbà pàtàkì fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn ayélujára, Ọgbẹni Ọlayinka Michael Fafoluyi tí pariwo síta fáwọn alako ìjọba wí pé kò sí ọ̀nà tí wọn lé gba láti fi ṣí àwọn aráàlú lọ́kàn láti mọ ìjọba aráàlú. 

Àná tí í ṣe Mọnde ni Ọlayinka Fafoluyi t'awọn èèyàn tún ń pè ní Solace sọ̀rọ̀ náà wí pé àwọn ọmọ àti olùgbé ìpínlẹ̀ náà tí làjú kọjá sísọ, tí wọn sì mọ ìtumọ̀ ìjọba awaarawa yàtọ̀ sáwọn ìjọba tó ti kọjá lọ.

O ni kò sẹni tó lè tọwọ bọ ọpọlọ àwọn ará ìpínlẹ̀ náà láti gba pe Gómìnà AbdulRazaq kí í ṣe ẹni tó yẹ kí wọn tẹ́lẹ̀, nítorí pé àwọn ipa rere tí AbdulRazaq tí kò laarin ọdún kan àti oṣù díẹ̀ tó dé ipò tí fi hàn pé kí í ṣe Gómìnà alatẹnujẹ. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o sọ pe "Àwọn ọmọ àti olùgbé ìpínlẹ̀ Kwara í imọ àti ọgbọ́n dáadáa, wọn si ni òye nnkan tó ń lọ. Ẹ kò lè tọwọ bọ ọpọlọ wọn láti gbagbọ nínú irọ́, àti pé àwọn ipa rere tí AbdulRazaq tí kò ti jẹ́ ẹ̀rí fáwọn èèyàn láti rí, kí wọn sì gbàgbọ́."


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI