NÍTORÍ KASNATY GBAJÚMỌ̀ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀, AAFA MẸ́RÌNDÍNLÓGÓJÌ WỌ ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 7, 2020

NÍTORÍ KASNATY GBAJÚMỌ̀ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀, AAFA MẸ́RÌNDÍNLÓGÓJÌ WỌ ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, àwọn Aafa tí kò dín ni mẹ́rìndínlógójì ni wọn ti wá nílùú Abẹ́òkúta tí í ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun báyìí láti gba àkànṣe àdúrà fún ìyàwó gbajugbaja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àgbáyé nnì, Kọ́láwọlé Àtàndá Adéjòjó to jáde láyé lọ́dún méjì sẹ́yìn, ìyẹn Alaaja Sẹmiat Oyíndàmọ́lá Àbẹ̀kẹ́ Adéjòjó.

Ọjọru tí i ṣe Wẹside ọ̀sẹ̀ yìí, ìyẹn ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹsàn-án ọdún 2020 ni yóò pé ọdún méjì gbáko tí Alaaja Sẹmiat jáde láyé lẹ́yìn àìsàn rampẹ.

AWIKONKO gbọ pé Alaaja Sẹmiat táwọn èèyàn tún ń pè ní Semmies jáde lẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì {36} nílùú Abẹ́òkúta, tí ikú rẹ sì ṣe pupọ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ni kàyéfì ńlá.

Ni báyìí, ọkọ rẹ̀, Kọ́láwọlé Adéjòjó táwọn èèyàn tún ń pè ní Kasnaty là gbọ pé ó ti ranṣẹ pé àwọn Aafa mẹ́rìndínlógójì káàkiri àgbáyé láti wá bá a ṣe àkànṣe àdúrà fún ìyàwó rẹ tó d'oloogbe náà.

Agbẹnusọ Kasnaty lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọgbẹni Michael Ọladipupọ to gbé ìròyìn náà si AWIKONKO létí jẹ́ kó ye wá pé agbegbe kan nílùú Abẹ́òkúta ni eto àkànṣe àdúrà náà yóò ti wáyé, tí wọn yóò sì ṣafihan rẹ lórí ìkànnì ayélujára tí Fesibuuku àti Instagiraamu. 

Ọgbẹni Ọladipupọ fi ye wá pé wọn kò fẹ́ èrò pupọ níbi eto àdúrà náà, ìdí rèé tó fi làwọn yóò ṣafihan bi eto naa ba ṣe ń lọ sí lórí ìkànnì ayélujára náà fáwọn èèyàn láti gbàdúrà pẹ̀lú wọn.

Ọkùnrin oniroyin náà tẹsiwaju pé wákàtí mẹ́ta gbáko ni wọn yóò fi ṣe àdúrà yìí.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI