GBAJUMỌ OṢERE TIATA WỌ GAU NITORI PASITỌ DELE OGUNDIPẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 9, 2020

GBAJUMỌ OṢERE TIATA WỌ GAU NITORI PASITỌ DELE OGUNDIPẸ


Ko ti i sẹni to le sọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si titi d'asiko ta a kọ iroyin yii tan lori bi gbajumọ Wolii nni, Wolii Ọladele Ogundipẹ t'awọn eeyan tun n pe ni Genesis ṣe gbe ọkan lara awọn oṣerebinrin Yoruba nni, Funmi Lawal lọ silẹ ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin la gbọ pe Funmi Lawal to ti kopa loriṣiriṣi ninu awọn fiimu agbelewo to jẹ ti Yoruba f'ẹsun jibiti owo ti ko din ni miliọnu meji naira kan Wolii Genesis.
 
Funmi ninu ẹsun naa lo ti sọ pe ilẹ kan ni Wolii Genesis fi lu oun ni jibiti, t'oun ko si ri owo naa gba pada, eyi to lo o m'oun pariwo sita.
 
AWIKONKO gbọ pe bi Funmi Lawal ṣe gbe ọrọ rẹ yii sita l'awọn eeyan ti pe akiyesi Wolii Genesis si i, ti wọn si lo o sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti Funmi fi kan oun, ati pe awọn ko jọ jokoo sọrọ ri.

Bi ọrọ Funmi ṣe tan kaakiri lo mu ki Wolii Genesis f'ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti lati ba a ṣe iwadii kikun, ti wọn si lọ ọ gbe Funmi nibi to wa lati fọwọ wa a lẹnu wo.
 
Lara awọn to gbe ọrọ naa si AWIKONKO lọọ jẹ ko ye wa pe n'ibi ti wọn ti n fọrọ wa Funmi lẹnu wo ni teṣan ọlọpaa to wa ni Alagbọn n'ilu Eko, to si ri ibi ti ọrọ naa n lọ ni wọn lo jẹ ko jẹwọọ fáwọn ọlọpaa wi pe irọ lasan loun pa mọ Wolii Genesis.
 
AWIKONKO ri i gbọ pe ẹni kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Bukky Jesse lo gbe owo fun Funmi Lawal lati ba Wolii Genesis lorukọ jẹ lati fi gba owo lọwọ ẹ.
 
Eyi lo mu k'awọn ọlọpaa f'ẹsun ibanilorukọjẹ kan Funmi, ti wọn si gbe e lọ s'ile-ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹbẹ lati ma ṣe f'oju ba ile-ẹjọ lo ja si pabo.
 
Lonii lo yẹ ki Funmi f'oju ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Igboṣere n'ilu Eko, ṣugbọn ti wọn i Funmi ko yọju sile-ẹjọ, bẹẹ ni agbẹjọro rẹ naa kọ lati yọju.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ile-ẹjọ naa ti sun igbẹjọ s'iwaju d'ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹrinla oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI